Ko si adura meji ti gbogbo awọn abiyamọ toootọ
aye maa n gba bi ko ṣe pe k’awọn jeere ọmọ wọn, ti wọn yoo si duro ti iru ọmọ
ti wọn ba fẹ jeere rẹ digbidigbi.
Wọn yii gan an l’ọrọ to lọ n’ibamu pẹlu b’awọn
eeyan kaakiri agbaye ṣe n ba Olukọ Agba Ede Yoruba nile Ẹkọ awọn Olukọni Agba t’ijọba
apapọ (Chief Lecturer, Federal College of
Education), eyi to fikalẹ si Oṣiẹlẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, iyẹn Ọmọwe
Aderẹmi Olusọji Fajẹnyọ yọ lori bi ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Iyanuoluwa Fanjẹyọ ṣe
kẹkọọ-gboye ni ile ẹkọ giga ti Ọgbin nilu Abẹokuta, iyẹn Federal University of
Agriculture (FUNAAB).
Ọjọ Iṣẹgun Tusidee
anaa ni eto ikẹkọọ-gboye naa ti waye ni Fasiti Ọgbin, iyẹn FUNAAB naa nilu
Abẹokuta, nibi t’awọn akẹkọọ ti ko din ni ẹgbẹrun kan ti kẹkọọ jade.
Lara awọn to kẹkọọ jade naa ni Iyanuoluwa
fajẹnyọ, to jẹ ọmọ Olukọ Agba ti FCE, Oṣiẹlẹ Abẹokuta yii, to si jẹ pe ọpọ awọn
eeyan ni wọn ṣi n ba idile Fajẹnyọ dunnu lori bi ọmọ wọn ṣe ṣe aṣeyọri.
Ẹka ikẹkọọ n’ipa awọn ẹranko, iyẹn Animal Science
la gbọ pe Iyanuoluwa ti kẹkọọ jade, ti wọn si looo pẹlu awọn to gbajumọ daadaa
l’ẹka ikẹkọọ naa lori bo ṣe n tayọ ninu ẹkọ rẹ.
Iyanuoluwa |
B’awọn mọlẹbi ati ololufẹ gbajugba olukọ t’ọpọ awọn
eeyan n tọ ipasẹ rẹ yọ, ni gbogbo awa alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ IROYIN AWIKONKO naa
la n ba idile Fajẹnyọ yọ, ti a si n gba a l’adura pe ọmọ naa yoo tubọ ṣe
aṣeyọri ti ko l’ẹgbẹ l’aye.
Bakan naa la tun n gba a l’adura pe baba naa yoo
jẹun ọmọ pẹẹpẹẹpẹẹ lagbara Ọlọrun to da aye ati ọrun, ti ounjẹ ọmọ naa ko si
nii koro l’ẹnu rẹ.
Diẹ tun re e l'ara awọn fọto ayẹyẹ naa:
Congratulations
ReplyDelete