Epe rabandẹ-rabandẹ l'awọn to gbọ s'iṣẹlẹ naa n gbe iyaale ile ọmọ ogun ọdun kan ṣẹ, lori bo ṣe gun ọkọ rẹ, to si tun duro ti i.
Bo tilẹ jẹ pe titi d'asiko ta a fi kọ iroyin yii tan la ko ti i gbọ n'ipa nnkan to da ija silẹ laaarin iyaale ile naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Makoduchukwu Ndubisi ati ọkọ rẹ, John Bosco Ngu ta a gbọ pe ọmọdun marundinlogoji (35), ṣugbọn ta a gbọ pe ohun ti wọn jọ n fa ko to nkan.
Ojule kẹrindinlogun, adugbo Donking, nsugbe to wa n'ijọba ibilẹ Anambra East, Anambra n'iṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yii.
ọkọ rẹ to gun pa |
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si jẹ ko ye wa ọkan ni ọmọbinrin naa ti gun ọkọ rẹ pa pẹlu ọbẹ, ṣugbọn t'awọn ara agbegbe naa sare gbe e lọ si ọsibitu Boromeo to wa ni Onitsha lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn to ku ki wọn too debẹ.
Wọn l'obinrin naa ṣi wa ni teṣan ọlọpaa nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo, ki wọn too foju rẹ bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment