Ko sẹni to de gbajumọ ọja Sabo to wa niluu Ṣagamu
l’ọjọ Iṣẹgun Tusidee anaa ti ara aje ko ta n’igba ti ọja naa jona di eeru, eyi
to fi awọn dukia ti ko din ni ogun miliọnu ṣofo danu.
Gẹbẹ bi a ṣe gbọ, wọn ijamba ina naa ko ṣẹyin
ileeṣẹ amunawa, iyẹn Ibadan Electricity Distribution Company, IBEDC ti wọn mu
ina mọna-mọna wa ni nnkan bi aago kan oru, ti wọn si ni ina naa pọju ohun to yẹ
ki wọn de lọ.
A gbọ pe bi wọn ṣe tan ina naa, ṣe lo bẹrẹ sii
tako ara wọn, ti awọn waya ina si bẹrẹ sii jọna, ko to pada kọja afẹnusọ. Awọn
ti wọn wa nibẹ l’asiko naa la gbọ pe wọn sare ranṣẹ pe ileeṣẹ panapana, to si
jẹ pe loju ẹsẹ l’awọn yẹn naa ti de.
Ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana too de, wọn ni aṣọ
ko bọmọyẹ mọ, tori pe ọpọ dukia at’awọn ọja ni wọn ti ṣofo danu, ko da, ti wọn
loo tun mu awọn ile kan to sunmọ ọja naa, ṣugbọn ti wọn ri diẹ pa.
Gomina Dapọ Abiọdun t’ipinlẹ Ogun ti wa a b’awọn
eeyan naa kẹdun pupọ lori ijamba ina naa, to si loun ti yan awọn igbimọ ti yoo
ṣẹ gbogbodukia to ba ijamba naa lọ, k’ijọba le tete f’awọn eeyan ni iranlọwọ to
ba yẹ.
Bẹẹ lo sọ pe ijọba yoo kọ ọja naa pada si eyi ti yoo dẹkun iru awọn ijamba ina bayii lọjọ iwaju.
No comments:
Post a Comment