O TAN O, ỌBASANJỌ PADA S'OKO AGBẸ RẸ, KAKARAKA LO N ṢIṢẸ BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 7, 2020

O TAN O, ỌBASANJỌ PADA S'OKO AGBẸ RẸ, KAKARAKA LO N ṢIṢẸ BAYII

Pupọ awọn to n ri fọto Aarẹ tẹlẹri l'orilẹ-ede Naijiria nigba aye ologun ati alagbada, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo n ṣe ni kayeefi wi pe ki lo le ṣẹlẹ si baba naa, to fi di pe ada ati ọkọ rẹ lo tun pada mu bayii, to si n tẹra mọ-ọn iṣẹ agbẹ karakara.

B'awọn kan ṣe n sọ pe nnkan ko dan mọnran fun Oloye Ọbasanjọ daadaa mọ, lo jẹ ko gba oko ẹ to wa ni Ọta lọ, lati lọọ wo awọn nnkan to le ri ta nibẹ, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe Baba yi kan lọọ gbafẹ lasan ni, ṣugbọn t'awọn mi-in n sọ pe nnkan ko fi bẹẹ lọ deede mọ fun un lo jẹ ko gba oko rẹ lọ.

Ko si nnkan meji to jẹ ki ọrọ Oloye Ọbasanjọ to ṣe Aarẹ alagbada l'orilẹ-ede yii lẹẹmeji ọtọọtọ maa jẹ iyalẹnu. bi ko ṣe ọwọ to fi mu ada ati ọkọ rẹ, to si n kanra mọ iṣẹ takun-takun.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn to ri Baba Iyabọ, ti wọn tun n pe ni Ẹbọra Owu nibi to ti n ṣiṣẹ ninu oko lo n fi Baba naa rẹrin, ti wọn ni ko yẹ ko tun maa da ara rẹ laamu mọ, ati pe awọn agbaṣẹ ṣe lo yẹ ko gbe iṣẹ oko rẹ fun un, nitori pe asiko lati fọwọ lẹran maa jẹun lo wa yii.


Nigba to n sọrọ, agbẹnusọ Baba naa lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi sọ pe kii ṣe pe nnkan ko lọ dee de mọ fun Oloye Ọbasanjọ lo ṣe gba oko rẹ lọ, ṣugbọn lati jẹ k'awọn eeyan, paapaa awọn ọdọ mọ pe owo wa n'idi iṣẹ agbẹ, nitori naa lo ṣe fẹẹ fi apẹẹrẹ lelẹ.

Bẹẹ lo tun ni Baba fẹẹ jẹ k'awọn eeyan mọ pe digbi lara oun ṣi le lati ṣiṣẹ to ba yọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI