O ṢEE ṢE KI AARẸ BUHARI MA KỌJA ỌDUN 2020 - WOLII JOSIAH - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 7, 2020

O ṢEE ṢE KI AARẸ BUHARI MA KỌJA ỌDUN 2020 - WOLII JOSIAH

Gbajugbaja Wolii to ni ṣọọṣi Christ Foundation Miracle International Chapel to wa niluu Eko, Wolii Josiah Onuoha Chukwuma ti sọ pe lara awọn nnkan ti Ọlọrun fi han an oun ni pe Buhari yoo kuro n'ipo ki ọdun 2020 too pari, bo tilẹ jẹ pe oun ko le fidi ẹ mulẹ nipa bi yoo ṣe ṣẹlẹ.

Wolii Josiah lo sọrọ yii ninu asọtẹlẹ rẹ f'ọdun 2020 ti a wa yii. O ni bi wọn ko ba rọ Aarẹ Buhari loye, wọn yoo yọọ kuro nipa aisan ti yoo kọluu lojiji.

Bẹẹ lo sọ pe Ọlọrun yoo tu aṣiri awọn ayederu pasitọ at'awọn babalawo to n pe ara wọn ni oloṣelu l'orilẹ-ede yii.


Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo ri ewu, rukerudo! Buhari ni lati ṣọra rẹ. Bi Aarẹ ba fi la awọn nnkan ti yoo d'oju kọ ọ ja, gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fi han, lati asiko yi titi di ipari oṣu kọkanla ọdun yi, o maa lo asiko rẹ tan. Ṣugbọn pẹluu nnkan ti mo ri yi, wọn yoo yọ Buhari kuro n'ipo rẹ, yala nipa irọloye tabi nipa aisan. Eyi ni nnkan ti mo le sọ nipa ẹ.


“Ọlọrun tun fi to mi leti wi pe Oun yoo tu aṣiri awọn onijibiti, ayederu Wolii, paapaa awọn babalawo to n pe ara wọn ni Ojiṣẹ Ọlọrun. Ayanmọ kan naa lo n duro f'awọn ologboni to n pe ara wọn ni oloṣelu, nitori pe ohun ti gbogbo wọn gboju le ni yoo d'oju ti wọn l'ọdun yi. Ọpọ awọn oloṣelu ni wọn yoo padanu awọn nnkan ti wọn gbojule. Ẹ jẹ ki wọn pada sọdọ Ọlọrun bi wọn ba fẹẹ ri igbala."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI