NNKAN ỌMỌ ỌKUNRIN TO POORA TI PADA, ṢUGBỌN KO ṢIṢẸ MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 29, 2020

NNKAN ỌMỌ ỌKUNRIN TO POORA TI PADA, ṢUGBỌN KO ṢIṢẸ MỌ

Laipẹ yii la mu iroyin kan wa fun un yin nipa nnkan ọmọ ọkunrin baba arugbo kan to pooora laarin ọja, ti baba naa si fẹsun kan gendekunrin kan wi pe o mọ nipa bi kinni abẹ oun ṣe lọ.

A sọ fun un yin n'igba naa pe Baba arugbo naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Papa Ejima bu sẹkun nigba ti kinni naa d'ọfẹ, to si mu k'awọn eeyan fẹẹ dana sun gendekunrin yii ko too di pe awọn ọlọpaa gba a silẹ.


Ṣugbọn ni bayii, iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe nnkan ọmọ ọkunrin Papa Ejima ti pada sii labẹ, ṣugbọn ti ko ṣiṣẹ bo ṣe yẹ ko ṣiṣẹ mọ bayii, ti wọn si ni ṣe ni baba naa n sunkun kaakiri.

Awọnt o gbe ọrọ naa si AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe Papa Ejima n sọ pe oun ko le tọ (urinate) rara titi d'asiko yii, to si ni gbogbo ileri ti ẹni to jẹ ki kinni naa poora n sọ ni pe ọsẹ yii ni kinni naa yoo pada, ti yoo si maa ṣiṣẹ, ṣugbọn to ni ko ri bẹẹ rara.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Oboro, By Niger nipinlẹ Umuahia n'iṣẹlẹ naa ti waye l'ọsẹ to kọja yii.

A gbọ pe aaya (tiger nuts) ni Papa Ejima ra l'ọwọ gendekunrin Hausa naa, ti wọn si ni bo ṣe san owo tan, ni gendekunrin naa f'ọwọ kan aṣọ rẹ bi ẹni to fẹ ba a yọ idọti nibẹ.

Nibẹ la gbọ pe ara ti fu Papa Ejima, to si yẹ nnkan ọmọkunrin rẹ wo, ṣugbọn ti ko ri nnkankan nibẹ mọ, ko too di pe o pari sita pe k'awọn eeyan gba oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI