Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta - Titi d'asiko ti a fi ko iroyin yii jọ tan l'awọn abiyamọ tootọ ṣi n gbe iya agba kan, Mama Vera ṣepe la-nla, lori bo ṣe fi ata wẹ awọn ọmọ-ọmọ ẹ meji ti wọn jẹun tori pe wọn ko gba aṣẹ lọwọ ẹ.
Bo tilẹ jẹ pe kayeefi niṣẹlẹ ti wọn loo ṣẹlẹ lagbegbe Mgbuoba, ijọba ibilẹ Akpor n'ipinlẹ Rivers naa ṣi n jẹ f'awọn eeyan, sibẹ ohun t'awọn eeyan n sọ ni pe ọdaju abiyamọ ni obinrin ẹni ọdun mejilelaadọta naa.
Ọmọdun meje ati mẹjọ ni wọn pe ọjọ ori awọn ọmọ naa, ati pe ohun to tun jẹ ki ọrọ naa Iya naa maa ya awọn eeyan lẹnu pupọ ni bi wọn ṣe ni Mama yii tun ṣe de awọn ọmọ naa mọlẹ bi aja pẹluu ṣẹkẹṣẹkẹ.
A gbọ pe Mama Vera kii tọju awọn ọmọ naa daadaa, ati pe l'asiko to fi ṣe awọn ọmọ-ọmọ rẹ yii baṣu-baṣu, ko f'awọn ọmọ naa l'ounjẹ, eyi lo mu ki wọn lọọ bu Gaari sinu omi, ti wọn si muu.
Wọn ni bo ṣe pada dele, to rii pe awọn ọmọ naa ti mu Gaari, lo ti bẹrẹ sii lu wọn, to si gbe ata to ṣẹṣẹ lọ, eyi ti wọn lo fẹẹ fi se ọbẹ, to si daa le wọn lori, lẹyin eyi ni wọn loo de wọn mọlẹ.
Awọn araale ti wọn jọ n gbe la gbọ pe wọn ja ilẹkun wọle lati gba awọn ọmọ naa silẹ, awọn ti ara abiyamọ ta la gbọ pe wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si lọọ gbe e.
No comments:
Post a Comment