NIKE FẸẸ GBE AṢỌ TUNTUN JADE F'AWỌN AGBABỌỌLU SUPER EAGLES - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 31, 2020

NIKE FẸẸ GBE AṢỌ TUNTUN JADE F'AWỌN AGBABỌỌLU SUPER EAGLES

Ileeṣẹ kan to n ṣe aṣọ ati bata kaakiri agbaye, iyẹn NIKE ti kede sita wi pe gbogbo eto lo ti pari bayii lati gbe aṣọ ẹgbẹjọda, iyẹn Jersey tuntun sita f'awọn agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria.

Ọjọru Wẹside ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ karun-un oṣu keji ọdun yii la gbọ pe wọn fẹẹ fi aṣọ tuntun naa sita f'awọn eeyan lati tete maa ko o ni kẹtikẹti.

Aṣọ tuntun yii la gbọ pe wọn ṣ'agbekalẹ ẹ n'igba ti eyi ti wọn gbe jade fi gba idije ife ẹyẹ agbaye l'ọdun 2018 ko ipa rere, pẹlu b'awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria kaakiri agbaye ṣe ra aṣọ naa kọja sisọ.


A gbọ pe fun ipalẹmọ ati igbaradi fun idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ (African Cup of Nations) to fẹẹ waye l'ọdun 2021 ati ti ife ẹyẹ agbaye to n bọ l'ọdun 2022 ni wọn ṣe gbe aṣọ tuntun naa jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI