Gbajugbaja oṣerebinrin tiata nni, Mercy Aigbe ti sọ pe oun ti ti ile ọmọ oun pa patapata, t'oun ko si n'ifẹ lati l'oyun, depodepo wipe oun yoo tun b'imọ mi-in laye mọ.
Mercy, iya ọlọmọ meji ti ko si n'ile ọkọ kankan l'asiko yi lo sọrọ naa laipẹ yii, n'igba to gbe fọto kan s'ita lori ikanni ayelujara ti insitagiraamu rẹ, eyi to fi ṣ'abẹwo sile awọn ọmọ alailobii.
O ni ko wu oun lati bimọ mọ, nitori pe meji toun bi naa ti to oun n wo titi aye, idi ni yii to fi loun ti ti ile ọmọ oun pa.
Ṣa o, ohun t'awọn ololufẹ Mercy n sọ ni pe ohun to le ṣe ni ko lọ yọ ile ọmọ rẹ danu to ba mọ pe oun ko fẹẹ b'imọ laye mọ ju meji to ti bi silẹ naa lọ, nitori pe niwọn igba to ba ṣi n sunmọ awọn baba olowo ẹ, o ṣee ṣe ko loyun lojiji.
No comments:
Post a Comment