GOMINA ABIỌDUN YAN AWỌN KỌMIṢANA RẸ LẸYIN OṢU MẸJỌ, L'ỌRỌ MI-IN BA TUN B'ẸYIN YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 10, 2020

GOMINA ABIỌDUN YAN AWỌN KỌMIṢANA RẸ LẸYIN OṢU MẸJỌ, L'ỌRỌ MI-IN BA TUN B'ẸYIN YỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta - Ireti gbogbo awọn ara ati olugbe ilu ni pe ki Gomina yan awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni kete ti wọn ba ti bura fun un, to si ti gba ọpa aṣẹ lati bẹrẹ iṣakoso, ṣugbọn ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ko ri bẹẹ latigba to ti de ọfiisi.

Ko si nnkan meji ti wọn loo pẹ ki Gomina Abiọdun too kede awọn ti yoo lo gẹgẹ bii Kọmiṣana ti wọn yoo jọ ṣiṣẹ pọ, bi ko ṣe pe o ṣẹṣẹ de ipo oṣelu ni, to si ni lati farabalẹ daadaa, ko le ṣe aṣeyọri to lọọrin daadaa.

Ni kete ti Ọmọba Dapọ Abiọdun fi orukọ awọn Kọmiṣana sita, to si tun fi ranṣẹ s'ile igbimọ aṣofin pe ki wọn bu ọwọ lu wọn, l'awọn araalu ti n woye ipo t'ẹnikọọkan wọn yoo di mu.

Lonii tii ṣe Ọjọ Ẹti, Furaidee ni Ọmọba Dapọ bura f'awọn Kọmiṣana mọkandinlogun ni gbọngan Aṣa, iyẹn Cultural Centre to wa ni Kutọ, niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.

Awọn Kọmiṣana naa ni:
Ọnọrebu Afọlabi Afuapẹ - Ijọba ibilẹ ati Ọrọ Oye Jijẹ (Local Government and Chieftaincy Affair)

Ọnọrebu Tunji Akinosi - Ọrọ Inu Igbo (Forestry)

Ọjọgbọn Sidi Ọṣọ - Eto Ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ-Ẹrọ (Education, Science and Technology

Ọmọwe Adeọla Ọdẹdina  - Iṣẹ Agbẹ ati Ọgbin (Agriculture)

Ọgbẹni Ọlaolu Ọlabimtan - Eto Iṣuna ati Agbekalẹ (Budget and Planning)

Amofin Gbọlahan Adeniran - Eto Idajọ (Justice)

Dọkitọ Tomi Coker - Eto Ilera (Health) 

Amofin Fẹmi Ogunbanwo - Iṣẹ Akanṣẹ (Special Duties)

TPL Tunji Ọdunlami - Eto Agbegbe ati Ayika (Urban and Physical Planning)

Ọnọrebu Abiọdun Abudu-Balogun - Eto Ayika (Environment)

Arabinrin Kikẹlọmọ Longe - Eto Idagbasoke Ileeṣẹ (Commerce and Industry)

Ọgbẹni Dapọ Okubadejo - Eto Iṣuna (Finance)

Ọnọrebu Oludọtun - Eto Idagbasoke Agbegbe (Rural Development)

Ọnọrebu Ganiyu Hamzat - Idagbasoke Agbegbe ati Ẹgbẹ Alajẹṣẹku (Community Development and Cooperatives)

Arabinrin Funmi Efuwape - Eto Awọn Obinrin (Women Affairs)

Ọgbẹni Kẹhinde Oluwadare - Ọrọ Ọdọ ati Ere Idaraya (Youth and Sports)

Ọgbẹni Jamiu Ọmọniyi - Ọrọ Ilegbee (Housing)

Ọgbẹni Toyin Taiwo - Eto Irin-ajo Igbafẹ (Tourism)

Ọgbẹni Ade Akinsanya - Ọrọ Iṣẹ ati Idagbasoke (Works and Infrastructure)

Eyi ti wọn lo tun n jẹ kayeefi lẹyin ti Gomina Abiọdun kede ipo f'awọn Kọmiṣana tuntun wọnyii, ti ko si mẹnuba ipo Ọrọ To N Lọ, iyẹn Information, ipo ti wọn loo ṣe pataki julọ ninu ijọba, ti ko si tun sọrọ lee lori wipe boya awọn ṣi n wa ẹni ti yoo di ipo naa mu.

Ohun t'awọn eeyan n sọ ni pe bi ipo naa ko ba si, ko ṣee ṣe ki kudiẹ-kudiẹ ma ṣẹlẹ ninu ijọba, ati pe ijọba ti ko ba ni ẹni ti yoo di iru ipo bẹẹ mu ṣetan lati fẹ idi ara rẹ sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI