Bo tilẹ jẹ pe, awọn Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti l'awọn wa l’ẹnu
iwadii iku gbajumọ oniṣegun ibilẹ nni, Alaaji Abdul-Fatai Yusuf ti gbọgbọ aye mọ
si ỌKỌ OLOYUN, ṣugbọn ti wọn ko tii fi abajade iwadii naa s'ita d'asiko ta a ṣ’akojọpọ
iroyin yii tan.
Ẹ o ranti pe, gbara ti wọn pa Ọkọ Oloyun, awọn Ọlọpaa
ni awọn ti n f’ọrọ
wa awọn Ọlọpaa meji to tẹ le e at’awọn
oṣiṣẹ rẹ kan l’ẹnu wo, ṣugbọn ta a gbọ pe, awọn Ọlọpaa ri aṣiri nla kan gbọ pe,
o ṣee ṣe k'awọn oṣiṣẹ abẹ Ọkọ
Oloyun kan at’awọn to sun mọ ọn pupọ mọ nipa iku rẹ.
Ọga Ọlọpaa kan n'ipinlẹ Ọyọ to ni ka ma ṣe darukọ oun
ni, aṣiri iwe jibiti t'awọn oṣiṣẹ Ọkọ Oloyun ṣe lo tu
si ọkunrin naa l'ọwọ, ti wọn
si sare dana sun awọn iwe naa. O ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe wọn mọ nipa iku alaaanu ọpọ eeyan naa lati bo aṣiri wọn to tu si i l’ọwọ.
![](https://blogger.googleusercontent.com/img/b/R29vZ2xl/AVvXsEjnhcluTkr-ea4iANu13ZeeZAZSPt99FgLwYGk1ZgRY9aeQk2pGRoiKDYORa_-eAmCa8q3nZl3oUh_qDQf_bFmTiXbyClu41ND-V5_MogFrjdo6Zgc9itLTSrkW52fpYgFYEXMdLMzz7eY/s1600/IMG_ORG_1580281117582.jpeg)
Gbogbọ
eyi ni Ọga Ọlọpaa naa ni iwadii awọn de duro lati mọ ibi ti iku gbajumọ oniṣegun
ibilẹ naa ti wa. Ṣa o, aṣiri
nla tu si wa l’ọwọ pe, oṣu
kejila ọdun to
kọja ni Ọkọ Oloyun gba awọn ayewe-owo-wo (auditor) lati ṣewadii bi owo ṣe n wọle ati bo ṣe n jade n'ileeṣẹ rẹ, paapaa n'igba ti
gbese awọn onibaara Option C pọ l'ọrun rẹ.
Nibẹ laa gbọ pe, aṣiri obitibiti owo t'awọn oṣiṣẹ Ọkọ
Oloyun kan ṣe baṣu-baṣu ti tu si i l’ọwọ. L'ọjọ t'iṣẹlẹ iku rẹ
naa ṣẹlẹ, otẹẹli ni Ọkọ
Oloyun wa n'ipinlẹ Ogun t'iyawo rẹ fi pe e pe, awọn kan dana sun awọn iwe
pataki kan ni ọfiisi rẹ.
L'ẹyin wakati diẹ si asiko naa ni Ọkọ Oloyun gba ipinlẹ Ọyọ lọ, ki wọn too pa a si oju ọna Igbo-Ora. Awọn ara
agbegbe t'iṣẹlẹ naa ti sele ti wọn s'oro ni, iṣẹlẹ naa s'oju awọn. Ọkunrin ọlọkada
kan ni agbegbe naa to n jẹ Dauda Ọjediran
ni, agbegbe Akeroro l'oju ọna
Eruwa si Igbo-Ọra n'ipinlẹ
Ọyọ ni wọn pa Ọkọ Oloyun si.
O ni, aṣọ
dudu l'awọn to pa ọkunrin
naa wọ, ati pe Ọkọ Oloyun nikan ni wọn kọlu ninu awọn ti wọn jọ kọwọọ rin. O jẹ ko di mimọ pe, aarin ibudo awọn Ọlọpaa
oriṣiiriṣii meji ọtọọtọ ni wọn pa Ọkọ Oloyun si. O fi kun un pe, bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ
ijinigbe pọ l'oju ọna ọhun
daadaa, ṣugbọn ti ko si ipaniyan iru ti Ọkọ Oloyun bẹẹ.
Ọkunrin to n fi ọkada rẹ na ọna ọhun daadaa wa be ijọba pe, awọn fijilante lo le ṣẹgun
wahala ọna naa. O ni, owo l'awọn Ọlọpaa oju ọna ohun maa n gba l’ọwọ awọn t'awọn
jẹ ọlọkada, to si ni ọpọ igba t'awọn Ọlọpaa ba ri awọn
ajinigbe ati oniṣẹ ibi ni
wọn maa n bọ aṣọ ọlọpaa
l'orun, ti wọn yoo salọ, koda to ni wọn yoo ni awọn naa l'ọmọ n'ile, ṣugbọn to l'awọn fijilante ni ki i bẹru,
ti wọn maa n k'oju awọn oniṣẹ ibi.
Araalu
mi-in to tun s'ọrọ ni, awọn
to pa Ọkọ Oloyun ti n tẹ le e
tipẹ, ti wọn si n ṣọ ọ titi
ti wọn fi f'ibọn pa a
nipakupa. Tiṣa, iyẹn olukọ to kọ Ọkọ Oloyun n'ileewe Muslim High School to wa l'agbegbe Ikọtun n'ipinlẹ Eko, iyẹn Alagba Adeyẹmi Okeronbi
t'oun naa n gbe agbegbe ti wọn pa Ọkọ Oloyun si ni, awọn agbanipa lo pa a.
O ni, gẹgẹ
bii Ọga ẹgbẹ OPC t'oun jẹ tẹlẹ ati
b'oun ṣe jẹ balogun ẹgbẹ awọn oniṣegun ibilẹ niluu Igbo-Ọra, o da oun l'oju pe, awọn ẹṣọ aabo ibilẹ lo le yanju eto aabo agbegbe ọhun nitori to ni b'awọn Ọlọpaa ba gbọ ariwo taya mọto to bẹ lasan, niṣe ni wọn
maa n salọ, ṣugbọn to l'awọn fijilante ki i bẹru.
O fi
kun un pe, idagbasoke agbegbe awọn ni Ọkọ Oloyun wa fun lati da ileeṣẹ silẹ, ṣugbọn to ni wọn pa a nipakupa.
Ṣa o, ọrẹ Ọkọ Oloyun
kan to s'ọrọ ni, ọrọ owo
nla kan pa Ọkọ Oloyun at'awọn kan pọ, to si
lo ṣee ṣe ko jẹ awọn eeyan naa lo ran awọn agbanipa si i, ṣugbọn to ni awọn diẹ ni aṣiri ọrọ owo
naa han si.
Ọkọ
Oloyun funra rẹ ko ṣai fura
pe, awọn kan n lepa ẹmi rẹ
ko too ku. Lati ọjọ Aje, iyẹn
Mọnde ọsẹ to lọ yii
titi d'Ọjọru, iyẹn Wẹsidee to ku ọjọ kan ṣoṣo ti
yoo ku ni Ọkọ Oloyun ti n kọ awọn ọrọ ifura si ori ẹrọ ayelujara Fesibuuku (Facebook) rẹ.
Niṣe ni gbajumọ oniṣegun ibilẹ naa n sọ pe, ki Ọlọrun gba oun l’ọwọ awọn to sunmọ oun bii iṣan ọrun, ti wọn n ba oun jẹ, ba oun mu, ṣugbọn ti wọn
n lepa oun kiri.
L'akootan,
ọjọ Abamẹta, iyẹn Satide ọsẹ yii ni
adura Fidau yoo w'aye fun un n'ile igbafẹ Ọkọ
Oloyun Fun City to wa ni Hotel bus
stop ni Igando, ipinlẹ Eko nibi t'awọn eeyan yoo ti pejọ lati ṣedaro
ati lati gbadura fun akọni nla
to lọ.
Awọn fọto ti ẹ tun n
wo yii ni awọn ileeṣẹ Ọkọ Oloyun to wa ni titipa ni ana yii at'awọn eeyan to
f'owo d'oko-owo Option C l'ọdọ rẹ ti wọn
ya lọ s'ileeṣẹ rẹ l'ọsẹ to kọja lati beere owo wọn. Bi gbọgbọ nnkan ba ṣe n lọ ni ẹ o maa gbọ
ni ikanni yii
Lati: Yoruba Tootọ.
No comments:
Post a Comment