Gomina Nasir El-Rufai tipinlẹ Kaduna ti pariwo sita wi pe ko si nnkan meji to n fa ọwọ ago idagbasoke orilẹ-ede Naijiria lọ sẹyin bi ko ṣe ti iṣoro ina mọnamọna t'awọn ọmọ orilẹ-ede naa n koju
Ilu Abuja ni El-Rufai ti sọrọ yii nibi ipade awọn agbaagba, iyẹn NEC, eyi ti igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi ọṣinbajo lewaju ẹ. Nibẹ lo si ti bu ẹnu atẹ lu ipo ti ọrọ ina mọnamọna orilẹ-ede Naijiria wa lasiko yii, paapaa bi wọn tun ti ṣe sọ ọ di ti aladani.
El-Rufai ta a gbọ pe oun ni wọn fi se adari igbimọ Ad-Hoc to ṣagbeyẹwo awọn to n ṣakoso ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna, iyẹn Electricity
Distribution Companies (DISCOs) l'oṣu kọkanla ọdun to kọja kanminu lori ipo ti ẹka naa wa, to si jẹ ko ye awọn eeyan pe ijọba apapọ labẹ Aarẹ Buhari ti na owo ti ko din ni tiriliọnu kan ataabọ (N1.7
trillion) nairan laarin ọdun mẹta si asiko yii.
No comments:
Post a Comment