Titi d'asiko ti a ṣ'akojọpọ iroyin yii tan l'awọn ara ọja Balogun to gbajumọ daadaa n'ilu Eko ṣi n banujẹ lori bi ina nla kan ṣe jo gbogbo ẹru wọn, to si sọ ọpọ wọn si kolobo aye.
Ko din ni ile meje ti wọn jona di eeru, ti meji lara awọn ile naa si wo lulẹ lasiko ti ọja naa to wa l'adugbo Martins ati Sunny Adewale l'agbegbe Lagos Island n jona lọwọ ati lẹyin to jona tan.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ karun-un oṣu kejila ọdun to kọja ni ọja yii jona, to si fi ọpọ dukia ṣofo danu.
A gbọ pe ọkan lara awọn to n ta'ja ninu ile naa lo tan ẹrọ jẹnẹretọ, ti jẹnẹretọ naa si ti n ṣiṣẹ lọ. Ko pẹ la gbọ pe awọn ni jẹnẹretọ naa lọ ra epo bẹntiroolu lati fi si i. Ibi to ti n da bẹntiroolu naa si lọwọ lo ti gbana l'ojiji.
Bo tilẹ jẹ pe ere ni wọn kọkọ pe e n'igba ti ina naa bẹrẹ si i jo, ṣugbọn ti wọn ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana l'oju ẹsẹ, ti wọn si ni ko pẹ t'awọn yẹn naa fi de.
Eyi gan la gbọ pe o jẹ ki ina naa tubọ ran s'awọn ile to ku l'agbegbe yii, to si fi awọn dukia ti ko din ni ọgọrun miliọnu ṣofo danu.
Ọga agba ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko, iyẹn Lagos
State Emergency Management Agency, Ọmọwe Olufẹmi Ọkẹ-Ọsanyintolu sọ pe nnkan bi aago mẹwaa aarọ anaa l'awọn eeyan ranṣẹ pe ileeṣẹ wọn, to si jẹ pe loju ẹsẹ l'awọn ti debẹ.
Ọkẹ-Ọsanyintolu lo jẹ ko ye wa pe ẹni to ni ṣọọbu ti ina naa ti bẹrẹ tun ko awọn kẹẹgi bẹntiroolu sinu ṣọọbu, eyi gan an lo tubọ jẹ ki iṣẹlẹ naa kọja sisọ, to si gb'awọn eeyan lamọnran wipeki wọn sọra fun bẹntiroolu lasiko yii, paapaa ina ijọba t'awọn eeyan n tan silẹ ki wọn too jade nile wọn.
No comments:
Post a Comment