EEMỌ N'IBADAN: ỌMỌ IYA MẸTA JONA MỌ'LE LỌJỌ KAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 3, 2020

EEMỌ N'IBADAN: ỌMỌ IYA MẸTA JONA MỌ'LE LỌJỌ KAN ṢOṢO

Ọla Eyitayọ, Ọyọ 

Asiko yi kii ṣe asiko to dara rara fun idile kan ti wọn ni wọn padanu ọmọ mẹta l'ọjọ kan ṣoṣo, iyẹn l'asiko t'awọn eeyan ṣi n yọ ayọ pọpọn-ṣinṣin ọdun tuntun ti a bọ si yii.

Aarọ onii, tii ṣe ọjọ ninu ọdun 2020 n'iṣẹlẹ buruku naa waye ladugbo Ẹhin Grammar, lagbegbe Mọlete, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

A gbọ pe awọn obi awọn ọmọ mẹta yi ko si nile lasiko iṣẹlẹ naa. AWIKONKO gbọ pe Iya awọn ọmọ naa ti wọn n pe ni Iya Ara ti lọ sibiṣẹ alẹ to wa, n'igba ti wọn ni Baba wọn naa ti ba tiẹ lọ, to si ti awọn ọmọ mẹtẹẹta mọ inu ile, iyẹ ni alẹ Ọjọbọ, Tọsidee ana.

Bo tilẹ jẹ titi d'asiko ta a fi ko iroyin yi jọ la ko tii mọ pato ohun to ṣ'okunfa ijamba ina naa, ṣugbọn ta a gbọ pe n'igba ti ina naa dee de ṣ'ẹyọ, awọn ọmọ yi ko ri aaye sa jade, tori pe Baba ti t'ilẹkun mọ wọn.

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada wa a gbe oku awọn ọmọ yi lọ si mọṣuari l'ọwọ ọsan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI