ỌLAIDE ỌṢINUGA, LAGOS - Baale ile ẹni ogoji ọdun kan, Terry Ikechukwu Iheme la gbọ pe ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ bayii lori ẹsun wi pe awọn ọmọ rẹ meji lo sọ di iyawo ile lojiji, to si n ko ibasun fun wọn lojoojumọ.
Awọn ọmọ rẹ mejeeji yii la gbọ pe ọjọ ori wọn ko tii ju ọdun meedogun si mẹwaa lọ, ti wọn lo tun maa n f'iya jẹ awọn ọmọ naa, paapaa bi wọn ko ba ti gbọnran si i lẹnu.
Agbegbe Igbo-olomu, Agric nilu Ikorodu, iyẹn n'ipinlẹ Eko la gbọ pe Iheme n gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ yii, ọkan lara awọn awakọ agba nileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe opopona, iyẹn Hi-Tech ni wọn pe Iheme yii.
Bi aṣiri naa ṣe tu s'ọwọ awọn araadugbo ni wọn ti lọọ fi to awọn ọlọpaa Owutu leti, t'awọn yẹn naa ko si f'ọrọ ọhun falẹ rara, ti wọn fi lọọ gbe Iheme ninu ṣọọṣi, l'asiko ti isin nlọ lọwọ, iyẹn l'ọjọ Sande to kọja yii.
L'ẹyin ti wọn f'ọrọ wa l'ẹnu wo tan l'awọn ọlọpaa ri i pe o jẹbi awọn ẹsun naa, ti wọn fi f'oju rẹ ba ile-ẹjọ Majisireeti akọkọ to wa ni Ita-Ẹlẹwa, Ikorodu, nibi to ti sọ pe ki wọn f'oju aanu wo oun.
Gbogbo ẹbẹ ti wọn ni Iheme n bẹ lo pada ja si pabo, ti Onidajọ F.A Afeez si paṣẹ pe k'awọn ọlọpaa ṣi fi pamọ s'ahamọ wọn, lai faaye silẹ lati gba beeli ẹ. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji ọdun yii ni wọn yoo tun pada f'oju ẹ bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment