Ẹ WO OJU AWỌN PASITỌ TI WỌN N LỌ S'ỌRUN APAADI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 8, 2020

Ẹ WO OJU AWỌN PASITỌ TI WỌN N LỌ S'ỌRUN APAADI

Oludasilẹ ṣọọṣi Christ Apostolic Miracle Ministry, Apositeli Paul Okikijesu ti fi orukọ awọn Pasito to sọ pe wọn ko ni pẹ ẹ ku sita, ati pe bi wọn ba ku, wọn ko nii l'anfaaani lati ri ijọba Ọlọrun wọ, bi ko ṣe pe inu ina ni wọn n lọ.

Awọn Pasitọ to darukọ naa ni Pasitọ Enoch Adeboye to ni ṣọọṣi The Redeemed Christian Church of God, RCCG; Pasitọ Wiliam Fọlọrunṣọ Kumuyi ti ijọ Deeper Life Bible Church ati Biṣọọbu David Oyedepo ti ijọ Living Faith Church lo sọ pe ọlọrun fi han oun ninu asọtẹlẹ ọdun 2020.

“Bayii ni Oluwa wi, Iranṣẹ mi, ma jẹ ko ya ẹ l'ẹnu wi pe mo lọ sinu ijọ Ridiimu, mo si ṣakiyesi wi pe ko si aguntan kankan nibẹ ti mo le mu? Idi ni yii ti mo fi sọ pe ọrọ mi Adeboye ṣi n bọ. Mo ti fi too leti wi pe nnkan to ba wuu, o le di, ṣugbọn a ko nii gba a laaye sinu ile ologo mi.

“Oun naa funra rẹ mọ bayii, o si ti bẹrẹ lati maa tọrọ idariji. Ko da, to ba tọrọ idariji, to si yi pada, gbogbo to ti ku nipa ẹtanjẹ ati iwa agabagebe ẹ, ṣe o le ji wọn didi bii?

“Atunṣẹ meloo ni Reinhard Bonnke ṣe ko too di pe o ku. Ọmọ mi, mo ti sọ fun un wi pe ko bẹrẹ sii tun ile rẹ to, ọjọ atisun rẹ ti n sunmọ itosi.
“Adeboye ati Kumuyi ati Oyedepo, mo ti sọ fun wọn wi pe ki wọn tete maa ṣe atunto ile wọn, ki wọn si maa palẹmọ lati sun oorun ikẹhin wọn.

“Kọ eleyi silẹ nitori pe asọtẹlẹ mi yoo le koko f'ọdun 2020.

“bayii ni Ọluwa wi: Maa ranṣẹ si awọn eeyan yii lati ṣe atunṣe, boya wọn maa ṣagbekalẹ isọji tabi itusilẹ nla, bo si jẹ idanilẹkọọ nla ni wọn yo ṣe. O si gbọdọ jẹ eyi ti wọn yo ṣe idariji. Bi wọn ko ba si ṣe e, ko nii ya wọn l'ẹnu wi pe wọn ko nii wọ ile ologo mi."

1 comment:

  1. No one is completely holy before God. It is the grace of God that is abound towards us. Lord God have mercy and take us home in heaven. Eternal life

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI