E WO B'AWỌN AGBEBỌN ṢE P'AWỌN EEYAN N'IPAKUPA L'ABULẸ OLORI ILE IGBIMỌ AṢOFIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 29, 2020

E WO B'AWỌN AGBEBỌN ṢE P'AWỌN EEYAN N'IPAKUPA L'ABULẸ OLORI ILE IGBIMỌ AṢOFIN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu ibanujẹ ati aibalẹ-ọkan l'awọn araalu Kwatas to wa n'ipinlẹ Plateau wa titi d'asiko ta a ṣ'akojọpọ iroyin yii tan, lori b'awọn agbẹbọn kan tẹni'kẹni ko tii mọ ṣe yawọ ilu naa, ti wọn si p'awọn eeyan to wa nibẹ nipakupa.

Abule Kwatas to wa n'ijọba ibilẹ Bokos la gbọ pe olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Plateau, Ọnọrebu Titus Alams ti wa, bo tilẹ jẹ ohun ta a gbọ pe b'awọn agbebọn ṣe yawọ ibẹ ko lọwọ oṣelu kankan ninu.

 
Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin l'awọn Boko Haram ya wọ ilu kan n'ijọba ibilẹ Mangu, ti wọn p'awọn eeyan ti ko din ni mejila danu. Eyi to tun ṣẹlẹ l'oru ọjọ Aiku Sannde si ọjọ Aje Mọnde ijẹta yii tun n kan awọn eeyan lominu pupọ, ti wọn si n rawọ ẹbẹ s'ijọba apapọ lati tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn apanijaye yii.

Diẹ re e lara awọn ti wọn pa danu naa:
 

 

 








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI