Ẹ KU OJULỌNA OMI JOYOM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 3, 2020

Ẹ KU OJULỌNA OMI JOYOM

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Lara awọn nnkan to n gbe ẹda ati aye ro l'atigba ti Ọlọrun ti da ọrun ati aye ni Omi (Water), Ko si ẹda naa ti kii lo omi l'ojumọ yatọ bi iru ẹda bẹẹ ba n gba aawẹ biribiri, ni ko ni i jẹ ko sunmọ omi laarin asiko to ba n gba aawẹ yii.

Omi ṣe pataki n'igbesi aye ẹda ti Ọlọrun da, bẹẹ oriṣiriṣi omi lo wa ti a n mu. B'awọn omi kan ṣe dara lati mu fun ilera ara, bẹẹ l'awọn mi-in ku diẹ kaato, lara awọn omi t'ijọba orilẹ-ede yi fọwọ sọ'ya le lori lasiko yii ni Omi Joyom (Joyom Water).

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ileeṣẹ Joyom Enterprises lati bẹrẹ iṣẹ gbigbe omi mimu jade jakejado orilẹ-ede Naijiria, paapaa kaakiri ilẹ Yoruba.

Ajọ to n yẹ ounjẹ jijẹ ati lilo oogun wo lorilẹ-ede yii, NAFDAC ti fi ontẹ lu omi JOYOM, koda, ti ijọba Naijiria naa tun f'ọwọ sii pe l'ara awọn ileeṣẹ ti yoo mu igbe aye irọrun b'awọn araalu n'ileeṣẹ Joyom Enterprises.

Ilu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun ni ileeṣẹ wọn wa, Fun awọn to ba fẹẹ ṣe alagbata omi Joyom kaakiri orilẹ-ede yii, 08069151224 ni ki ẹ pe fun ẹkunrẹrẹ alaye.

3 comments:

  1. Eleyi je idagbasoke to muna doko ni eka eto omi pipon ni abuda eto ilera..aseyori nla leleyi je fun ile ise joyom and gbogbo omo ile kaaro oojiire..mo gba ladura wipe ki olorun tubo gbe ile ise joyom lowo soke

    ReplyDelete
  2. Mr yomi ojo..aka PA,aka christian lubotin, agba awo of nigeria...owo yin a ma roke....

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI