Pẹlu bi aarun aṣekupani kan ti wọn pe ni Coronavirus ṣe n tan kaakiri agbaye bayii, ati b'awọn oniṣegun ko ṣe ti i ri ọna abayọ si i, a ni lati maa la ara wa l'ọyẹ lojoojumọ lori bi a ṣe le d'ẹkun kiko aarun yii.
Aarun yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni aarun Coronavirus yii tun buru ju awọn aisan ati aarun to ti j'ẹyọ tẹlẹ bi i Lassa, HIV/AIDS, Ẹbola at'awọn mi-in.
Awọn orilẹ-ede wọnyii ni aarun naa ti tan de bayii, to si pa awọn eeyan ti ko din ni aadọta.
China
United States
France
Japan
South Korea
Taiwan
Singapore
Thailand
Australia
Nepal
Vietnam
Hong Kong
Macau
Malaysia
Canada
Awọn to ti le ni ẹgbẹrun mẹfa la gbọ pe wọn ti ko aarun ti wọn ni orilẹ-ede China ni wọn ti kọkọ ri i yii.
Lati d'ẹkun rẹ, A ni lati maa fọ ọwọ wa loore-koore pẹlu ọṣẹ ati omi, bi ko ba si si omi n'itosi, a le lo ogogoro tabi awọn kẹmika ti wọn fi n fọ ṣalanga (sanitizer)
Ẹ ma jẹ k'awọn ọmọ yin maa gbe awọn ohun ọsin bi i adiẹ, aja, ewurẹ, tabi fi ọwọ pa kokoro l'asiko yii. Bẹẹ ni ẹ ko gbọdọ f'ọwọ lasan gbe eku ti ẹ ba pa, ati pe adiẹ tabi ẹran to ba ti ku, ẹ ma ṣe gbiyanju lati jẹ ẹ tori pe o lewu pupọ.
Imọtoto b'ori aarun m'ọlẹ bi ọyẹ ti n b'ori oru. Abọ ọrọ la n sọ fun ọmọluabi, to ba de inu rẹ, yoo di odindi.
No comments:
Post a Comment