Ẹ F'ỌWỌSOWỌPỌ GBE IJỌBA LARUGẸ - IGBAKEJI GOMINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 29, 2020

Ẹ F'ỌWỌSOWỌPỌ GBE IJỌBA LARUGẸ - IGBAKEJI GOMINA

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti gb'awọn araalu lamọnran wi pe ojuṣe gbogbo araalu ni lati f'ọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati le jẹ k'ijọba ṣe aṣẹyọri to gunrege.

Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa nilu Ọta Awori, ipinlẹ naa nibi eto ayẹyẹ ọdun marundinlaadọta (45years) ti wọn da ẹgbẹ Iganmọdẹ Club silẹ, eyi to waye n'ile ẹgbẹ naa to wa n'ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta. nibẹ lo si ti sọ pe igbega ipinlẹ Ogun, ojuṣe gbogbo araalu ni, kii ṣe ijọba nikan.

Bakan naa lo sọ pe b'awọn ara ati olugbe ilu Ọta-Awori ba fi le f'ọwọsowọpọ pẹlu Ijọba, anfaani nla ni yoo jẹ fun wọn jake-jade.

Salakọ-Oyedele sọ pe l'ara ifẹ ti Gomina Dapọ Abiọdun ni silu Awori lo jẹ ko yan igbekeji rẹ lati ilu naa, to si tun yan olori awọn oṣiṣẹ rẹ naa nibẹ pẹlu, eyi to sọ pe ko tii ṣẹlẹ ri ninu itan ipinlẹ naa.

O jẹ ko ye awọn eeyan pe l'ara awọn ifẹ ti Gomina Abiọdun ni si wọn lo jẹ ko bẹrẹ awọn iṣẹ akanṣe nibẹ laarin oṣu mẹfa ti wọn de ijọba, eyi to sọ pe yoo tubọ mu idagbasoke de ba eto ọrọ aje nibẹ ni kiakia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI