CORONAVIRUS: RUSSIA L'AWỌN KO FẸẸ RI ỌMỌ CHINA L'ỌDỌ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 30, 2020

CORONAVIRUS: RUSSIA L'AWỌN KO FẸẸ RI ỌMỌ CHINA L'ỌDỌ WỌN

Orilẹ-ede Russia l'Ọjọbọ Tọside anaa ti kede sita gbangba wi pe awọn yoo ti gbogbo ẹnubode wọn to wọle si orilẹ-ede China pa lati ma jẹ ki wọn wọle s'ọdọ wọn l'asiko yii.

Ko si nnkan meji to mu ki Alakoso (Prime Minister) orilẹ-ede Russia, Mikhail Mishustin sọrọ naa jade bi ko ṣe ti aarun kan to tun ṣẹṣẹ jade sita lasiko yii, eyi ti wọn pe ni Coronavirus.

Aarun naa la gbọ pe wọn ko ti i ri oogun rẹ titi d'asiko ta a ṣ'akojọpọ iroyin yii tan, to si ti n tan kaakiri awọn orilẹ-ede

Ko din ni eeyan 132 la gbọ pe aarun Coronavirus ti pa danu, ti wọn si l'awọn ti ko din ni ẹgbẹrun mẹfa (6000) l'awọn ti wọn ti ni aarun naa l'ara.

Pabambari ẹ ni bi wọn tun ṣe sọ pe orilẹ-ede mẹẹdogun ni aarun naa ti tan ka laarin oṣu kejila ọdun to kọja si asiko yii.

Ẹ fura o. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI