Titi di asiko ti a fi n ko
iroyin yi jọ niroyin naa ṣi n jẹ kayeefi fun gbogbo ara ati ọmọ ipinlẹ Ogun
latari bi ọkan lara awọn alaga ti yoo tukọ ijọba ibilẹ Ipokia fungba diẹ,
Ọnọrebu Shuiab Adeọṣun ṣe ku lojiji.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oni tii ṣe
Ọjọru, Wẹside lo yẹ ki ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ṣe ayẹwo mo peregede, iyẹn
screening fun ọkunrin naa, atawọn ti
wọn jọ yan sipo alaga kaakiri ijọba ibilẹ Ogun to wa n’ipinlẹ Ogun, ti wọn si
ni gbogbo lo ti n mura silẹ lati lọọ dahun orisirisi ibeere n’iwaju ile igbimọ
naa.
A gbọ pe ko si nnkan to ṣe
Ọnọrebu Shuiab Adeọṣun ni ana, Tuside, ti wọn si loun atawọn kan jọ ṣere tilẹ
fi ṣu ni alẹ ana ni, ko too di pe o lọọ sun un.
Bo tiẹ jẹ pe a ko tii le fidi
ohun to pa ọkunrin naa mulẹ, ṣugbọn lara awọn ahesọ to ta si AWIKONKO leti ni
pe ṣe l’ọkunrin naa ṣubu lasiko to fẹẹ wọ baluwẹ lati wẹ laarọ yii, to gbagbẹ
sọda sọrun alakeji.
B’awọn kan ṣe n sọ pe apeta ni
wọn pe Adeọṣun lati oju orun, bẹẹ l’awọn kan n sọ pe majele lo ṣee ṣe ki wọn
fun un, ṣugbọn ti a ko tii le fidi aṣiri iku ẹ mulẹ titi ta a fi kọ iroyin yii
tan. Ati pe lara awọn nnkan to tun ta si wa leti ni pe ayọ ayọju ni wọn loo fun
ọkunrin naa ni ẹjẹ riru, eyi tojẹ ko dunnu ku, ti ko si tete ri alaaanu.
Awọn mi-in tun sọ pe iku
ọkunrin naa kii ṣ’oju lasan, nitori pe o l’awọn ti wọn jọ n du ipo naa, ko too
di pe o ja mọ-ọn l’ọwọ, ṣugbọn ti wọn lo ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ti wọn ko gba ti
ẹ ni wọn sa sii, to fi ku lasiko to yẹ ko lọọ fi ara ẹ han n’iwaju ile igbimọ
aṣofin lati fi ontẹ luu.
Eyi ti a tun gbọ, to tun yatọ
diẹ ni pe wọn ni ọsibitu ni Adeọṣun wa, to ti n gba itọju lati bi i ọjọ meloo
kan sẹyin, ko da, ti wọn ni ori bẹẹdi gan an ni wọn ti fi too leti wi pe Gomina
ti fi orukọ rẹ ranṣẹ sile igbimọ aṣofin.
No comments:
Post a Comment