AWỌN AGUNBANIRỌ KAAKIRI NAIJIRIA GBA IROYIN TUNTUN, NI WỌN BA N DUNNU KAAKIRI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 31, 2020

AWỌN AGUNBANIRỌ KAAKIRI NAIJIRIA GBA IROYIN TUNTUN, NI WỌN BA N DUNNU KAAKIRI

Ko da, bi wọn ba gun ẹṣin ninu awọn agunbanirọ l'orilẹ-ede Naijiria, wọn ko ni i kọ'sẹ, to ri bẹ o to bẹe, o si ju bẹẹ lọ, pẹlu bi wọn ṣe gba owo ọya tuntun akọkọ ti ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn (33,000) naira.

Bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ t'awọn agunbanirọ to n sin orilẹ-ede baba wọn kaakiri Naijiria ti n reti iru nnkan bayii, ṣugbọn ti a gbọ pe ojiji lo ba gbogbo wọn l'ẹyin ti ijọba apapọ ti ṣeleri fun wọn pe oun yoo fi owo kun owo wọn.

Ṣe la gbọ pe pupọ wọn gba ilu, ti wọn si bẹrẹ si i jo kaakiri, n'igba ti owo naa bẹrẹ si i wọle sori foonu wọn lati nnkan bi aago meji ọsan oni Ẹti, Furaide.

Ọkan lara awọn agunbanirọ to wa nipinlẹ Ẹnugu, Joseph Odichi n'igba to n ba ọkan l'ara awọn oniroyin sọ pe bi ala lo ṣi ṣe n ri l'oju oun, ati pe oun ko le sọ bi inu oun ṣe dun to, n'igba ti owo naa wọle s'ori foonu oun. O ni "Furaide rere lonii yii jẹ fun gbogbo wa."

Bakan naa, Arowoṣẹgbẹ Busayọ t'oun naa jẹ agunbanirọ sọ pe oun ko ti i gbagbọ pe loootọ ni, n'itori pe lati oṣu kẹrin ọdun to kọja l'awọn ti n reti owo yii, ṣugbọn ti Ọlọrun ti pada ṣe e bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI