AWỌN AGBA MUSULUMI Ṣ'ABẸWO SI ỌỌNI ILE-IFẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 30, 2020

AWỌN AGBA MUSULUMI Ṣ'ABẸWO SI ỌỌNI ILE-IFẸ

Ẹ di opo Islam mu gidigidi - Ọba Adeyẹye Ogunwusi

Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II ti gba gbogbo awọn mususlumi jake-jado lamọnran wi pe ki wọn di opo ẹsin Islam, ki ẹ si maa tẹle awọn ilana ẹsin naa gẹgẹ bi iwe mimọ Kuraani (Quran) ṣe f'idi ẹ mulẹ, paapaa bi Ojiṣẹ Ọlọun Muhammed ṣe gbe e kalẹ.

Image may contain: 2 people, people on stage and indoor 
Arole Oduduwa, Ọba Adeyẹye sọrọ yii l'asiko to n gb'awọn agba ẹgbẹ musulumi kan l'orilẹ-ede Naijiria, iyẹn Ansar-Ud-Deen Society of Nigeria, ẹka t'iluu Eko l'alejo ni Aafin ẹ to wa n'iluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun l'ọjọ Aje Mọnde to kọja yii.

Image may contain: 3 people, people standing 
Ninu ọrọ Kabiyesi, Ọba Adeyẹye sọ pe "Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ti a si tun n gbọ lati ẹnu awọn ọjọgbọn ati olori ẹsin, Islam jẹ ẹsin alaaafia, eyi si la gbọdọ duro le lori. A gbọdọ jẹ ẹni to n gbe alaaafia larugẹ ninu iṣe ati ihuwasi i wa, paapaa awọn ẹlẹsin mi-in.

Image may contain: 3 people, indoor 
"A gbọdọ maa ba ara wa ṣe lai lo ẹta inu tabi ikoro-ọkan nitori pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọrun ti a n sin. Awọn Kirisitẹẹni, Musulumi at'awọn mi-in la jọ n sin Ọlọrun kan-naa, ṣugbọn l'ọna ọtọọọtọ"

Image may contain: 8 people, people standing 
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Imaamu agba to lewaju awọn eeyan naa lọ lo ti sọ pe gbe oṣuba rabandẹ fun Ọọni, to si ṣ'apejuwe Ọọni gẹgẹ bi ojiṣẹ Allah to ti n lo gbogbo awọn nnkan to ni lati fi sin Ọlọun.
Image may contain: 4 people, people standing

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI