AWỌN ADIGUNJALE ATAWỌN ỌLỌPAA KỌJU IJA SIRA WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 10, 2020

AWỌN ADIGUNJALE ATAWỌN ỌLỌPAA KỌJU IJA SIRA WỌN

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna n'igba t'awọn ọlọpaa at'awọn adigunjale kọ'ju ija sira wọn, t'ọrọ naa si fẹẹ di ogun abẹle, iyẹn nijọba ibilẹ Danmusa, ipinlẹ Katsina Local Government Area of the state.

A gbọ ṣe l'awọn adigunjale naa ji ọmọdebinrin, ọmọdun mẹrinla kan, Lantana Haruna gbe, eyi ni wọn loo jẹ k'awọn ọlọpaa lọọ koju wọn, tọrọ naa si di iṣu ata yan-an-yan-an

N'igba to n fidi iṣẹlẹ na amulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Gambo Isah sọ pe ọjọ mejidinlogun sẹyin ni wọn ti ji ọmọbinrin naa gbe lagbegbe Tashar Mai Alewa, ti wọn si n beere owo lati fi gba a silẹ.

Ọmọ ti wọn ji gbe
O ni l'ẹyin iwadii l'awọn rii pe agbegbe Jigawar-Sawai l'awọn eeyan naa wa, eyi lo jẹ k'awọn pinnu lati lọọ koju wọn, to si ni b'awọn adigunjale naa ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn ti kọ'ju ibọn si wọn, t'awọn naa si da a pada loju ẹsẹ.

Bẹẹ lo fi kun un wipe awọn ri meji mu balẹ ninu awọn adigunjale naa, ati pe loju ẹsẹ ni wọn ti ku.

AWIKONKO gbọ pe awọn meji ti wọn ku naa ni Gambo Balejo ati Ali Dan Maishago.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI