ASISAT OSHOALA S'OKO ỌRỌ S'AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA TI WỌN KO D'IBO FUN LATI JAWE OLUBORI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 10, 2020

ASISAT OSHOALA S'OKO ỌRỌ S'AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA TI WỌN KO D'IBO FUN LATI JAWE OLUBORI

Gbajugbagba agbabọọlu obinrin fun Orilẹ-ede Naijiria nni, Asisat Oshoala ti ti ju bọmbu ọrọ s'awọn ọmọ Naijiria marun-un ti wọn ko d'ibo fun un lati jawe olubori fun obinrin to mọ bọọlu gba julọ n'ilẹ Afrika, eyi to waye l'ọrilẹ-ede Egypt l'ọjọ Iṣẹgun Tusidee to kọja yii.

Asisat to tun jẹ ogbontarigi ninu ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lo gba aami ẹyẹ ajo ere idaraya n'ilẹ Afrika, iyẹn CAF t'ọdun 2019, to si jẹ pe eyi to gba yii ni ẹlẹẹkẹrin iru ẹ to maa gba.

Ọdọmọbinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn naa lo gba a l'ọdun 2014, 2016 ati 2017.

L'ẹyin eto idibo ati ayẹyẹ naa, ni ajọ to ṣagbekalẹ ẹ ti gbe bi eto idibo naa ṣe lọ sita, to si f'oju han pe awọn ọmọ Naijiria marun un to wa nibẹ l'ọjọ naa ni wọn ko d'ibo fun un.

Bi esi naa ṣe jade sita ni Asisat ti gba ori ikanni ayelujara ẹlẹyẹ nni, iyẹn Twitter rẹ lọ, to si lọ kọ ọ sibẹ wi pe Eniyan ki ba ti jẹ Ọlọrun ni, ko ba ma ṣee ṣe f'oun lati gba aami ẹyẹ naa walẹ, ati pe oun dupẹ pe pẹluu bi ọjọ ori oun ṣe kere to, oun mọ awọn to ti dide lati ara  aṣeyọri oun.

Ajara Nchout lati orilẹ-ede Cameroon ati Thembi Kgatlana toun wa lati orilẹ-ede South Africa ni Asisat f'ẹyin wọn gbolẹ, lati fi jawe olubori naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI