AMẸBỌ FẸẸ FI AAMI ẸYẸ IGBELARUGẸ AṢA DA AKINRỌGUN ADEWALE L'ỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 10, 2020

AMẸBỌ FẸẸ FI AAMI ẸYẸ IGBELARUGẸ AṢA DA AKINRỌGUN ADEWALE L'ỌLA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta - Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, gbogbo eto lo ti pari bayii fun ileeṣẹ AMEBO ONLINE NEWSPAPER lati fi aami ẹyẹ da Akinrọgun Victor Mọbọlaji Adewale l'ọla.

Ọjọru tii ṣe Wẹside, iyẹn ọjọ kẹẹdogun oṣu yii ni eto idalọla naa yoo waye ni gbọngan 10 DEGREE to wa ni Ikẹja, ilu Eko (10 Degree hall, Ikeja, Lagos State).

Gẹgẹ bi atẹjade ti alaga igbimọ aami ẹyẹ naa ti wọn pe ni Amebo Media Award, Ọgbẹni Michael Ọladipupọ fi sita, eyi ti ẹda rẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, O ni kii ṣe pe awọn deede fẹẹ da ọkunrin to n gbe Aṣa ati Iṣe Yoruba larugẹ kaakiri agbaye naa lọla, bi ko ṣe lati fi mọ riri awọn ipa rẹ lagboole Aṣa Yoruba.

O ni aami ẹyẹ t'awọn fẹẹ fun ọkunrin naa yoo jẹ koriya f'awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye lati mọ riri nnkan ti wọn gbe dani, eyi t'awọn Oyinbo ti fẹẹ ko lọ tan, k'awọn naa si le tẹra mọ Aṣa ajogunba wọn.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe kii ṣe Akinrọgun Adewale nikan ni yoo maa gba aami ẹyẹ. O ni oṣu meji gbako ni eto ayẹyẹ naa yoo fi waye, nitori pe gbogbo awọn ti wọn n mọ riri ileeṣẹ Amebo Online Newspaper l'awọn yoo da lọla rẹpẹtẹ.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI