VGN, ẸGBẸ́ ỌLỌ́DẸ ÀTI OJULALAKANFINṢORI GBE OṢUBA KÁRE FÚN KỌMIṢANA ỌLỌPAA TUNTUN NIPINLẸ OGUN, EBRIMSON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 7, 2019

VGN, ẸGBẸ́ ỌLỌ́DẸ ÀTI OJULALAKANFINṢORI GBE OṢUBA KÁRE FÚN KỌMIṢANA ỌLỌPAA TUNTUN NIPINLẸ OGUN, EBRIMSON

Ẹgbẹ Fijilante tijọba apapọ, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, ẹka tipinlẹ Ogun; ẹgbẹ́ Ogun State Hunters Association ati Ẹgbẹ́ Ojulalakanfinṣori ti gbe oṣuba kare fun Kọmiṣana ọlọpaa tuntun nipinlẹ naa, Kenneth Ebrimson fun akitiyan rẹ lati mu iwa ọ̀daràn wa sopin pátápátá. 

L'Ọ́jọ́bọ (Tọside) tó kọjá yí ni Kọmiṣana Kenneth Ebrimson báwọn ileeṣẹ eleto aabo yí ṣèpàdé láti mọ ọna ti wọn yoo gba rán ara lọ́wọ́, paapaa bi ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun ṣe ń wọlé bọ̀.

Nigba tó ń b'AWIKONKO sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ẹti (Furaide) àná, Ọ̀gá àgbà ẹgbẹ́ VGN nipinlẹ Ogun, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin sọ pé koriya ni ipade náà jẹ, torí pé yóò tún ro gbogbo ileeṣẹ eleto aabo lágbára pupọ pẹluu bí ileeṣẹ ọlọpaa tún ṣe fún wọn ní ifọwọsowọpọ. 

Bẹ́ẹ̀ lo sọ pé nínú àwọn igbesẹ tí Ebrimson ń gbé, pàápàá fún tí ìpàdé tí wọn ṣe, ó ti fi hàn dájú pé ẹni tí kò nii gba igbakugba, tàbí fi ọ̀rọ̀ eto ààbò ṣeré rárá. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ síwájú, ó sọ pé "Níbi ìpàdé yí ni Kọmiṣana Kenneth Ebrimson tí gbé oriyin fún wa, àtàwọn ọmọ iya wa yòókù lórí igbiyanju wá nípa eto ààbò, fún tí ifọwọsowọpọ wá pẹluu wọn. 

"Bí ẹ bá wo nnkan ti Kọmiṣana ṣe pẹluu ipade yi, ẹ máa ṣàkíyèsí pé akíkanjú, ẹni ọwọ, olórí pípé ọkùnrin ni ẹni ti wọn gbe wa fun wa, tori pe ọna lati rii pe eto aabo gboopọn sii lo n fẹ, ọna tuntun to tun fẹ ni lati fọwọsowọpọ pẹluu ẹgbẹ Fijilante, ọlọdẹ atawọn VGN yoo jẹ ko tubọ ṣe aṣeyọri to peregede, nitori pe awa naa ti pinu lọkan ara wa wipe gbogbo nnkan to ba n fẹ la maa fun un.

“Gbogbo nnkan ti yoo ba si na wa lati rii pe awọn ọdaran fi ipinlẹ silẹ la maa sa gbogbo ipa wa le lori, kii ṣe awọn ọdaran nikan, gbogbo awọn to ba n ni erongba lati huwa ọdaran yoo kọwọ wọn bọ aṣọ. Awa la sunmọ araalu julọ, ti ọrọ agbegbe wa si ye wa yekeyeke.”

Alaga ẹgbẹ Ẹgba-Ọmọ-Liṣabi Ojulalakanfinṣori Network, Alaaji Bello Alade Muhammed ninu ọrọ to b’AWIKONO sọ lo ti sọ pe “Ọga ọlọpaa tuntun yi lo ranṣẹ si wa pe ka waa ṣepade papọ, a sọrọ lori eto aabo, ti wọn si jẹ ko ye wa pe awa la mọ bi agbegbe wa ṣe ri, ti a le ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati mu alaafia ba ilu, ka si fọwọsowọpọ pẹluu wọn.

“Bo tilẹ jẹ pe a tun ṣi maa ṣe ipade min in lati jẹ ki wọn mọ awọn iranlọwọ ti awa naa ma nilo lọdọ wọn, sibẹ, igbesẹ ti ọga ọlọpaa tuntun yi gbe jẹ iwuri, ti mo si rii gẹgẹ bi ẹni to mọ nnkan to n ṣe. Inu mi dun pupọ fun ipade naa, ti a si ti ṣetan lati bawọn ṣiṣẹ papọ, ki irọrun le ba gbogbo araalu ati agbegbe ẹ.

Nigba to n sọrọ lori ẹgbẹ wọn, o ni ọdun 1995 lawọn ti wa, tawọn ti n ṣiṣẹ aabo, “Vigilante Group of Egbaland lorukọ ti a n jẹ tẹlẹ, ko too di pe a lọọ fi orukọ tuntun silẹ lọdọ ajọ to n forukọ ileeṣẹ silẹ lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn CAC. Inu ẹgbẹ wa lawọn ẹgbẹ bii PCRC, VGN, SO-SAFE CORPS ti jade, ti a si n ṣiṣẹ wa bo ṣe yẹ."

Nigba to n sọrọ lori ipalẹmọ wọn fun ayẹyẹ ọdun keresimesi to n bọ lọna, “Kọmiṣana sọrọ kikun lori asiko taa wa yi, lori bi a ṣe maa ṣiṣẹ papọ, bo tilẹ jẹ awa naa ti ni eto nile funra wa. Gẹgẹ bi a ṣe mọ wipe awọn kan wa ti wọn ko fẹẹ ṣiṣẹ rara, yatọ si ki wọn jale, ti wọn si fẹẹ wa gbogbo ọna lati ri owo, a ti sọ funfun gbogbo awọn eeyan wipe ki wọn gbaradi, ti a si ti ṣe oriṣiriṣi idanilẹkọọ fun wọn.

“A ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ niluu Ọyẹ-Ekiti laipẹ yi ṣẹlẹ nibi, tori ẹ lawa naa ṣe wa ni igbaradi fawọn oniṣẹ ibi, ti Ọlọrun si n ti wa lẹyin. A ko fẹ ki ọdaran kankan wọ ipinlẹ Ogun wa. Mo fẹẹ fi dawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun loju wipe wọn le sun ki wọn diju mejeeji, ati pe awọn naa gbọdọ fi iwa ọdaran to ba n lọ lagbegbe wọn to wa leti, tori pe iṣẹ aabo, ajọṣe ni fun gbogbo eeyan, ko ṣee da ṣe.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI