Kani kii ṣe pe awọn araadugbo wa n'itosi n'ibi ti baale ile kan ti wọn n pe ni Papa Ejinma ti lu iyawo d'aku ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe ibẹ ni iyawo rẹ yoo gba lọ s'ọrun alakeji, ti ko si nii l'anfaani lati pada ji s'aye mọ.
Ale ana tii ṣe Tusidee, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun to jẹ ọdun ku ọla la gbọ pe Papa Ejinma lu iyawo rẹ bi ilu, to si mu ki obinrin naa fi ori rẹ gba okuta nla kan niluu Azikoro to wa n'ijọba ibilẹ Yenagoa, ipinlẹ Bayelsa.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ni Papa Ejinma ko ṣẹṣẹ maa lu iyawo rẹ n'ilukulu, ṣugbọn ti alẹ ana yi ni wọn loo gba ọna min in yọ pẹluu bi obinrin naa ṣe daku ni nnkan bi aago mọkanla alẹ.
Awọn araadugbo to wa nitosi la gbọ wọn sare rọ omi le obinrin naa lori to fi ji s'aye pada lẹyin bi i iṣẹ mẹẹdogun, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
No comments:
Post a Comment