NITORI ẸSUN AGBERE, BAALE ILE LU IYAWO Ẹ DAKU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 7, 2019

NITORI ẸSUN AGBERE, BAALE ILE LU IYAWO Ẹ DAKU

"Mi o kabamọ pe mo lu iyawo mi" lọrọ ti wọn lo n tẹnu baale ile kan, Kofi Bandoli jade laipẹ yi nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ wipe o lu iyawo ẹ lalubami titi to fi daku.

Orilẹ-ede Ghana la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye nigba ti wọn sọ pe Kofi pe iyawo ẹ, Awutu Bereku lori foonu, ṣugbọn ti ko gbe e, to si pinu lati lọọ wo o nile, ko too di pe o ba ọkunrin lori iyawo ẹ, ti wọn jọ n gbadun ara wọn lọwọ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ko ṣẹlẹri ki Awutu ma gbe foonu ọkọ rẹ, Kofi, ẹni ọdun marunlelọgbọn (35), ti wọn si lọọ jẹ kayeefi fun Kofi nigba to pe iyawo titi, ṣugbọn ti ko gbe e.

Gbogbo erongba Kofi lori bi iyawo rẹ ko ṣe gbe foonu rẹ ni pe boya nnkan buruku ti ṣẹlẹ sii, idi ni yi to fi pinu lati lọọ wo nile, to si jẹ pe nigba ti yoo fi wọ yara, ibi ti Awutu ati ale to gbe wa sile ti n gbadun ara wọn karakara lo ti ba wọn.

Wọn ni kaka ki Kofi ki ale naa mọlẹ lati luu, iyawo ẹ lo doju ija kọ, to si luu titi to fi daku mọn ọn lọwọ. Asiko ti wọn ni Kofi n lu iyawo rẹ yi ni ale naa ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ.

Awọn to n gbọ ariwo la gbọ pe wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati wa a wo nnkan to n ṣẹlẹ, ti wọn si sare gbe obinrin naa lọ si ọsibitu Awutu Breku Hospital fun itọju, ṣugbọn ti Kofi ṣi wa lọgba ọlọpaa nibi to ti n kawọ pọyin rojọ lọwọ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI