KAYEEFI NLA: DỌKITỌ MẸRIN POKUNSO L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 2, 2019

KAYEEFI NLA: DỌKITỌ MẸRIN POKUNSO L'ABUJA

Aarẹ ẹgbẹ awọn Dọkitọ niluu Abuja, Dọkitọ Roland Aigbovo ti fidi rẹ mulẹ wipe ko din ni dọkitọ mẹrin ti wọn n ṣiṣẹ laarin ilu Abuja ni wọn dee de gba ẹmi ara wọn laarin oṣu kinni si oṣu kẹfa ọdun ti a wa yi.

Bo tilẹ jẹ pe Dọkitọ Aigbovo ko darukọ awọn dọkitọ naa, ṣugbọn o sọrọ yi nibi iwọde ti wọn ṣe lati fi polongo aṣilo oogun, ti wọn ṣe ninu ọja Wuse to wa niluu Abuja. 

O ni ọpọ awọn eeyan ni wọn n lo aṣilo oogun pẹluu ero lati dẹkun wahala ti wọn n koju lojoojumọ, eyi lo fa ti wọn ko fi mọ iru oogun to yẹ ki wọn lo bi ara ba n ro wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI