Kani gendekunrin ti ẹ n wo aworan rẹ yi mọ pe aye oun yoo pada bajẹ sọwọ awọn tọọgi, boya ki ba ti fi aye rẹ fun Jesu tabi Anọbi ko too di pe akara rẹ pada tu sepo.
Lọjọ Aiku Sande to kọja yi la gbọ pe gendekunrin naa ti a ko tii morukọ ré dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan pẹluu ọrẹ rẹ kan toun ti na papa bora lọọ ja baagi gba lọwọ obinrin kan lagbegbe Ajimele nipinlẹ Delta.
Obinrin naa la gbọ pe o kigbe ole le wọn lori lasiko tawọn mejeeji n ba ẹsẹ wọn sọrọ, ṣugbọn ti wọn fi ọkada le wọn, ṣugbọn to jẹ pe eyi ti ẹ n wo yi nikan lọwọ tẹ.
Awọn to gbe iṣẹlẹ naa si AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe loju ẹsẹ lawọn eeyan ti da igi jọ, ti wọn si ko bajinọtu iya fun un, ko da ti wọn lawọn kan ti gbe taya ati bẹntiroolu wa lati dana sun un, ṣugbọn ti wọn lawọn ẹlẹyinju aanu lo gba a silẹ.
Teṣan ọlọpaa la gbọ pe wọn pada gbe e lọ, nibi ti wọn ti tii mọ sẹẹli dasiko ta aṣakojọpọ iroyin yi tan.
Gbogbo akitiyan lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta sọrọ lo ja si pabo.
No comments:
Post a Comment