WỌN LU BAALE ILE PA LORI ẸSUN AGBERE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 20, 2019

WỌN LU BAALE ILE PA LORI ẸSUN AGBERE

Bi oku ba n ra kooro, baale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Pascal Uba yoo ti de ajulẹ ọrun bayii lori bi wọn ṣe lawọn tọọgi luu pa siwaju ile baba rẹ lori ẹsun wipe o fẹẹ fipa ba iyaale ile kan sun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe kan ti wọn pe ni Umuiwuogu to wa nijọba ibilẹ Mbaitoli, iyẹn nipinlẹ Imo niṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yi, ti wọn si ni iyaale ile naa, Arabinrin Ebere lo fẹsun kan an wipe o fẹẹ fipa ba oun laṣepọ.

AWIKONKO gbọ pe ara Pascal ko ya lati bi ọdun meloo kan sẹyin, idi ni yi ti wọn fi muu lati ilu Eko to n gbe wa sile Baba ati Iya rẹ nipinlẹ Imo.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ pato bọrọ naa ṣe jẹ, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe Ebere lo ko awọn tọọgi lọọ ba Pascal nile, ti wọn si luu lalubami. Wọn ni wọn ko fun ascal laaye lati sọrọ titi to fi ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI