ỌWỌ TẸ TẸGBỌN TABURO TI WỌN N LU JIBITI ORI AYELUJARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 22, 2019

ỌWỌ TẸ TẸGBỌN TABURO TI WỌN N LU JIBITI ORI AYELUJARA

Ṣe wọn ni ọmọ iya meji kii rewele ni, ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ l'Ọjọbọ Tọside ana nigba ti wọn lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo kumọ-kumọ, iyẹn EFCC wọ tẹgbọn taburo kan lọ sile ẹjọ sile ẹjọ giga tijọba apapọ to fikalẹ sipinlẹ Ẹdo lori ẹsun jibiti ori ayelujara.

Ohun ta a gbọ ni pe, ọpọ awọn eeyan lawọn tẹgbọn taburo ti wọn pe orukọ wọn ni Wisdom Onojiolou ati Omorodion Onojiolou ti lu ni jibiti obitibiti owo ti ko din ni miliọnu mẹẹdogun naira.

Obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Philian Uwadiae la gbọ pe wọn lu ni jibiti owo to to miliọnu mẹẹdogun ati ẹgbẹrun lọna irinwo naira (Fifteen Million, Four Hundred Thousand Naira) lori ẹtanjẹ wipe wọn fẹẹ da ileeṣẹ silẹ fun un niluu Benin.

 
Nigba ti wọn ni obinrin naa ko ri esi owo ti wọn gba lọwọ oun, lo jẹ ko tọ ajọ EFCC lọ lati fi to wọn leti, ko too di pe ọwọ palaba wọn segi.

NIgba to n sọrọ, Onidajọ M. G Umar sọ pe kawọn EFCC ṣi fawọn mejeeji pamọ digba ti igbẹjọ min in yoo tun waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI