ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ AYAWORAN LORILẸ-EDE NAIJIRIA, GBOGBO AGBOOLE AMULUDUN LO N KII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 19, 2019

ONI LAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ AYAWORAN LORILẸ-EDE NAIJIRIA, GBOGBO AGBOOLE AMULUDUN LO N KII

Oni tii ṣe ọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ni ayẹyẹ ọjọ ibi ọkan lara awọn gbajumọ ayaworan lorilẹ-ede Naijiria, Ọgbẹni Ibrahim Abdullahi Ọlatunde tọpọ awọn eeyan jake-jado mọ si Ibromercy.

Ko si nnkan meji to jẹ ki oni yatọ ninu gbogbo ayẹyẹ ọdun ti Ibromercy to jẹ ọkan pataki lara ọmọ ẹgbẹ ololufẹ gbajugbaja olorin Fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Ọdẹtọla tọpọ mọ si Pasuma, iyẹn Pasuma Fans Club bi ko ṣe pe ayẹyẹ ogoji ọdun rẹ laye lonii jẹ.
Idi ni yii ti gbogbo agboole amuludun lorilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye, paapaa awọn to mọ ọkunrin naa daadaa ṣe ti n fi atẹjiṣẹ loriṣiriṣi ranṣe sii lati kii ku oriire anfaani nla ti ogoji ọdun naa laye, nitori to jẹ Oore-Ọfẹ nla.

Yatọ si wipe Ibromercy jẹ gbajugbaja ayaworan, bẹẹ lo tun jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣere tiata ti TAMPAN nipinlẹ Ogun, to si tun jẹ ogbontarigi lara awọn ọmọ ẹgbẹ Igi Alọye, to si ti ko ipa ribiribi laarin wọn.
Bi wọn ba n ka awọn ayaworan to gbajumọ daadaa lagboole amuludun nipinlẹ Ogun lonii, ọkan ninu marun un ni wọn yoo ka Ibromercy mọ.
Yatọ si wipe gbogbo agboole amuludun ba ọkunrin naa yọ ayọ oriire ti ko wọpọ yi, ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL naa n fi asiko yi ba Ọgbẹni Ibrahim Abdullahi Ọlatunde yọ, ti a si n gba a ladura wipe ki Ọlọrun fun un ni ẹmi gigun ninu ilera pipe ati alaafia.
Ọkan pataki lara awọn to n gbe Iroyin Awikonk larugẹ ni Ibromercy, idi ni yi ti a ko fi le ma ṣai dupẹ lọwọ rẹ, ka si mọ riri awọn ipa to ti ko nileeṣẹ wa lati bi ọdun meloo kan sẹyin.
Igba ọdun, iṣẹju aaya kan ni yoo jẹ fun ọ pẹluu ogo Ọlọrun, ki Adẹdaa si ba wa da ẹ lohun gbogbo awọn ohun ti o n fẹ nipa oore-ọfẹ Rẹ. Amin.
























No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI