Ọ̀DARÀN TÍ KÒ BÁ RÌN JÌNNÀ SIPINLẸ OGUN YÓÒ WỌ GAU - GÓMÌNÀ ABIỌDUN PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 28, 2019

Ọ̀DARÀN TÍ KÒ BÁ RÌN JÌNNÀ SIPINLẸ OGUN YÓÒ WỌ GAU - GÓMÌNÀ ABIỌDUN PARIWO SÍTA


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun tí pàrọwà sí gbogbo àwọn ọ̀daràn tàbí àwọn tó ń gbìyànjú láti hùwà ọ̀daràn nipinlẹ náà wípé kí wọn rìn jìnnà réré kí wọn má bá a fi ẹ̀wọ̀n tàbí ikú ṣe ifajẹ.

O ni ìjọba òun kò nii faaye gba ìwà ọ̀daràn láàyè nítorí pé ààbò ẹni àti dúkìá pẹluu igbayegbadun àwọn èèyàn ló jẹ́ òun lógún, tó sì ṣe pàtàkì.

Gomina Abiọdun sọ̀rọ̀ yí lásìkò tó ń gba kọmiṣana ọlọpaa tuntun nipinlẹ náà, Kenneth Ebrimson lálejò ni ọ́fíìsì ìjọba tó wà ní Oke-Mọsan niluu Abẹ́òkúta l'Ọ́jọ́ru (Wẹsidee) àná. 

Ó ni bo tilẹ̀ jẹ́ pé ipinlẹ náà pààlà laarin awọn ìlú kan, tó sì tún pààlà pẹluu orilẹ-èdè min in, ìdí ni yìí tó fi jẹ pe anfaani ni yóò jẹ fáwọn ọ̀daràn láti gba ipinlẹ Ogun kọjá, ṣùgbọ́n síbẹ̀, kò sì ààyè fún wọn láti tẹ̀dó. 

Bẹ́ẹ̀ lo tún sọ pé loorekoore làwọn yóò máa gbìyànjú láti wá ọ̀nà ìgbàlódé tí wọn yóò fi máa dẹ́kun ìwà ọ̀daràn, nítorí pé àlàáfíà lo jẹ òun lógún.

Nínú ọ̀rọ̀ tìrẹ, Kọmiṣana tuntun náà, Kenneth Ebrimson sọ pé òun kò àga ìṣeré tàbí oorun wá nígbà tòun ń bọ̀, nítorí pé iṣẹ ààbò lòun wá á ṣe, tòun sì tún ṣetan láti ja láti dẹ́kun ìwà ọ̀daràn. 

Ó ní káwọn aráàlú lọọ fọkàn ara wọn balẹ nítorí pé ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọn wá lábé ààbò, tí kò sì nii ṣe pẹluu ẹlẹyamẹya. 




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI