O MA ṢE O, Ẹ WO OKU GENDEKUNRIN TI WỌN JU SOMI L'ANAMBRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 22, 2019

O MA ṢE O, Ẹ WO OKU GENDEKUNRIN TI WỌN JU SOMI L'ANAMBRA

Kayeefi niku gendekunrin kan ti wọn lawọn kan tẹnikẹni ko ti mọ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan ju somi, to si jẹ pe omi naa lo mu yo bamu to fi dagbere faye.

Awọn kan la gbọ pe wọn ri oku naa ko too di pe wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa.

Ko si nnkan meji to n ṣe ọpọ awọn eeyan ni kayeefi bi ko ṣe bi wọn ṣe de gendekunrin naa lọwọ sẹyin, ti wọn si luu lalubami ko too di pe wọn juu sinu odo nla.

 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ko ye wa pe awọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu St Michael to wa lagbegbe Umuoji fun ayẹwo iku to pa a.

Oun lo si tun fi kun un wipe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu lati mọ awọn to wa nidi iku gendekunrin naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI