NJẸ ẸYIN TI RI GODWIN, ỌMỌDUN MẸRIN TO SỌNU??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 4, 2019

NJẸ ẸYIN TI RI GODWIN, ỌMỌDUN MẸRIN TO SỌNU???

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu idaamu ati ibanujẹ ọkan ni awọn mọlẹbi ọmọdekunrin, ọmọdun mẹrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Godwin Goodluck wa bayii, latari bi wọn ko ṣe ri ọmọ naa lati bi oṣu kan sẹyin bayii.

Ogunjọ oṣu kẹwaa to kọja yi la gbọ pe wọn ko ti ri Godwin to n gbe lọdọ awọn obi rẹ niluu Ahoada, ipinlẹ Rivers. A gbọ pe lọjọ Aiku (Sande) ti wọn ri Godwin gbẹyin, ohun atawọn ẹgbọn rẹ pẹlu aburo rẹ ni wọn jọ n ṣere lasiko ti wọn lawọn obi rẹ naa ko si nile.

Ṣadede la gbọ pe wọn ko ri Godwin mọ, ti wọn si wa kaakiri gbogbo ibi ti wọn lero wipe o le wa, ko da, ti wọn tun lọ sawọn ibi ti wọn juwe fun wọn, ṣugbọn ti gbogbo rẹ ja si pabo.

Fun bi ọjọ marun la gbọ pe wọn fi duro wipe boya awọn ajinigbe ni wọn ji Godwin gbe, ṣugbọn ti wọn ko ri ipe lati ọdọ ẹnikẹni wipe boya wọn yoo beere owo lati gba a silẹ. Ọpọ redio ati amohunmaworan (tẹlifiṣan) ni wọn ti kede wipe wọn n wa Godwin, to si jẹ pe pabo ni.

A gbọ pe awọn ọlọpaa gan an ti bẹrẹ igbesẹ lati ri Godwin, tawọn naa ko si tii ṣe aṣeyọri kankan dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

AWIKONKO n fi asiko yi rawọn ẹbẹ si ẹyin ololufẹ wa wipe, bi ẹ ba kofiri tabi ṣalabapade Godwin Goodluck, ọmọdun mẹrin nibikibi, ẹ jọwọ, ẹ ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, tabi ki ẹ pe nọmba awọn obi rẹ yii 08026839722.

Ọlọrun ko ni jẹ ka ṣofo ọmọ o. Amin

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI