NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN JU MATHEW ATI MOSES SẸWỌN NI BENUE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 25, 2019

NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN JU MATHEW ATI MOSES SẸWỌN NI BENUE

Lọjọ Ẹti (Furaidee) ọsẹ to kọja yi ni Onidajọ Mọbọlaji Ọlajuwọn tile ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Makurdi, ipinlẹ Benue ju ọdọmọkunrin ọmọdun mejilelogun kan, Ajene Mathew Adikwu si ẹwọn ọdun kan gbako pẹluu iṣẹ aṣekara.

Ko si nnkan meji to mu ki wọn da ẹwọn ọdun kan fun Mathew bi ko ṣe ti jibiti ori ayelujara ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo kumọ-kumọ, iyẹn EFCC fi kan an lẹyin iwadii ti wọn ṣe nipa ẹ, toun naa si jẹri pe loootọ ni.

 
A gbọ pe pẹlu oju aanu ni Onidajọ fi da ẹjọ naa, to si tun fi aaye silẹ lati san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun (100,000) naira dipo ko lọọ ṣẹwọn ọdun naa nibamu pẹluu iwe ofin orilẹ-ede yi to nii ṣe pẹluu jibiti ori ayelujara tọdun 2015.

Lọjọ naa la tun gbọ pe wọn ju Baale ile kan, Moses Adukwu sẹwọn oṣu mẹfa pere ni kọọtu kan ṣoṣo yi, ṣugbọn toun naa si tun ri anfaani owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) naira latari bi wọn ṣe loun n fi ọpọ ayederu owo lu awọn araalu ni jibiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI