Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lagbegbe
Ibara to wa niluu Abẹokuta l'Ọjọru Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba ti wọn lawọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popona tipinlẹ Ogun, iyẹn TRACE lu ọlọkada Opay lalubami, tiyẹn si daku
laarin titi, eyi to mu kawọn ẹgbẹ rẹ naa wọya ija pẹluu wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni kii ṣe pe
oṣiṣẹ TRACE ta a ko tii m'ọruko rẹ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan dee de
lu ọlọkada Opay naa, bi ko ṣe ti ẹsun to fi kan an wipe ero to gbe lẹyin ko de
akoto sori gẹgẹ bi ofin ati ilana ti wọn gbe kalẹ fun wọn.
Awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO
leti jẹ ko ye wa pe ni nnkan bi aago meji ọsan niṣẹlẹ naa waye labẹ biriiji
Ibara, to wa nitosi Panṣẹkẹ niluu Abẹokuta.
Wọn ni ina to maa n da awọn mọto duro
lo da ọlọkada Opay naa atawọn mọto min in duro lọjọnaa, ọọkan ni wọn si ni oṣiṣẹ TRACE
naa ti n wo ọlọkada naa lọọkan pẹlu ero lati muu.
Ṣugbọn nigba ti wọn ni oṣiṣẹ TRACE naa
yoo fi debẹ, ina ti so pe kawọn mọto kọja, ori irin ni wọn ni TRACE yi ti fa ọkada naa mọn ọlọkada yi lọwọ, toun ati ero to gbe si ṣubu lulẹ, eyi ni wọn loo mu ki ọlọkada
yi fibinu sọrọ pe ṣe o fẹẹ pa awọn danu ni.
Ọrọ naa ni wọn loo bi oṣiṣẹ TRACE naa
ninu to fi bẹrẹ sii da igbaju bo ọlọkada Opay naa, ti wọn loo tun n fọ igi ọwọ
rẹ to mu dani mọn ọn, titi to fi ṣubu lulẹ.
Ere la gbọ pe awọn tọrọ naa ṣoju wọn kọkọ pe e, afigba ti
wọn rii pe ọlọkada naa ko min in mọ, awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn sare
lọọ gbe omi, ti wọn daa le lori, lẹyin bi iṣẹju marun la gbọ pe o pada taji
saye.
Lasiko ti won ni ọlọkada Opay yi daku
silẹ, lawọn ọlọkada ẹgbẹ ẹ ti paaki lati gbẹsan, ti wọn si ni asiko ti wọn fẹẹ
dana iya fun oṣiṣẹ TRACE naa lawọn yooku rẹ yọju, tọrọ naa si di isu ata yan an
yan.
Ko pẹ ni wọn lawọn ọlọpaa de bẹ, ti wọn
si bawọn yanju ọrọ naa. AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ re e tawọn oṣiṣẹ
TRACE yoo maa mu awọn ọlọkada Opay lori wipe awọn ero ti wọn n gbe kii fẹẹ lo
akoto, to si jẹ pe ọpọ igba lawọn ọga awọn Opay yi ti maa n kilọ fun wọn pe ki
wọn yee gbe ero ti ko ba ti gba lati lo akoto wọn.
Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ lori
iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi to jẹ agbẹnusọ fun TRACE jẹ ko di mimọ pe
ahesọ lasan lawọn eeyan n gbe kaakiri wipe TRACE lu ọlọkada, o ni ko si nnkan
to jọ bẹẹ rara, wọn kan fẹẹ ba wọn lorukọ jẹ lasan ni.
Bẹẹ lo tun jẹ ko ye wa pe ọlọkada naa tapa
si ofin ni, idi ni yii ti wọn fi ba a wi lori ẹṣẹ rẹ.
Ṣa o, ohun tawọn eeyan n sọ lori ọrọ
ti Akinbiyi sọ ni pe tani eṣinṣin ko ba gbe lẹyin, bi kii ba a ṣe elegbo, ati
pe awọn eeyan naa ko nii sọ eyi to n jẹ otitọ ọrọ nitori pe ohun to ṣoju awọn
eeyan gedegbe ni loun sọ pe ko ri bẹẹ.
No comments:
Post a Comment