NI POLI IBADAN, ỌRẸ MEJI KOJU ARA WỌN TORI ỌKUNRIN KAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 22, 2019

NI POLI IBADAN, ỌRẸ MEJI KOJU ARA WỌN TORI ỌKUNRIN KAN ṢOṢO

Fọnran kan to n lọ kaakiri ori ayelujara bayii ni tawọn ọrẹ meji kan ti wọn koju ara wọn lori ọkunrin ṣoṣo ni ile ẹkọ gbogboniṣe tiluu Ibadan.

Gẹgẹ bi fọnran naa to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe ṣalaye, gendebinirin kan lo fẹsun kan ọrẹ rẹ to pe ni Temi wipe o n ba ọrẹkunrin oun jade lẹyin, ṣugbọn ti aṣiri pada tu soun lọwọ.

Temi nigba toun naa n sọrọ sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun to fi kan oun nitori pe oun ko tẹle ọrẹkunrin rẹ jade, ati pe ko si otitọ ninu ahesọ to n gbọ lẹyin.

 
Ọpọ awọn to ri fọnran naa lo n ṣe ni kayeefi titi dasiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI