Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ tí sọ pé kò ṣeni tí yóò rí àwọn nǹkan tó ń lorilẹ-ede yí lónìí tí yóò sọ pé inú òun dùn, àti pé kò dá, bí Jésù Kristi gan án bá wà ní Nàìjíríà lásìkò yí, kò nii panumọ láti sọ̀rọ̀.
Ọbasanjọ sọ̀rọ̀ náà lọ́jọ́ Àìkú {Sande} àná níbi ayẹyẹ ipagọ ọlọdọọdun tí ṣọọṣi Four Square {Foursquare Gospel Church in Nigeria}, ọdún kẹrinlelọgọta irú ẹ tó wáyé ní Ajebọ, ipinlẹ Ogun.
Nibẹ ni wọn tún ti yàn Alakoso Agba àti Oludasilẹ tuntun fún ṣọọṣi náà, Rẹfurẹndi Samuel Aboyeji tó gbà ipò lọwọ Rẹfurẹndi Felix Meduoye
Ó ní ọ̀rọ̀ Nàìjíríà kò ṣeé panumọ fún lásìkò yí, tó sì tún ti gba wípé káwọn Ojisẹ Ọlọ́run gan án bẹ̀rẹ̀ sii sọ̀rọ̀ jáde síta. Bẹ́ẹ̀ lo gbawọn Kristẹni lamọnran wípé kí wọn máa hùwà bíi ti Jésù, kí wọn sì jẹ ki ìfẹ́, ìṣọ̀kan jọba laarin wọn láti má ṣe jẹ oúnjẹ fún ọ̀tá.
Nínú ọ̀rọ̀ ẹ, ó sọ pé "Gẹgẹ bii Onigbagbọ, a ní láti máa hùwà bíi Jésù, gẹgẹ bo se jẹ́ pé a dá wa bíi Jésù, tí a fara jọ ọ. Nítorí náà, ní gbogbo ọ̀nà, tàbí ipò yowu ká wá, a ní láti kó ara wa níjàánu.
"Bí Jésù bá wà niru ipò yí, tàbí nínú nkkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọwọ yí, kí ni kò bá ti ṣe? A ní ọ̀pọ̀ nnkan láti ṣe niru ipò tí a bá ara wa lorilẹ-ede yí lónìí.
"Fún emi, bí Kristi bá wà ní Nàìjíríà lónìí, kò nii panumọ. Ṣe ló máa sọ ojú abẹ nikoo. Ó máa sọ òtítọ́ fún àwọn alágbára. Kò nii bẹru, bẹ́ẹ̀ sì ni kò nii gbọjẹgẹ.
"Ẹyin ọmọ Ọlọ́run, ẹni ojúṣe láti ṣe, kí ẹ sọ àwọn nǹkan tí ẹ mọ wípé Jésù Kristi lè sọ tó bá jẹ́ pé òun náà wá ní Nàìjíríà lónìí."
Nigba tó ń gba olórí ìjọ tuntun náà lamọnran, ó ní kó gbìyànjú láti mú ìjọ náà gùn òkè àgbà, àti pé kii se ipele tó kàn (Next Level) bíi ti Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe fi polongo ibo rẹ.
No comments:
Post a Comment