MO FẸ́RÀN LÁTI MAA GBE FỌ́TÒ ÌDAJÌ IHOHO ARA MI SITA - GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2019

MO FẸ́RÀN LÁTI MAA GBE FỌ́TÒ ÌDAJÌ IHOHO ARA MI SITA - GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ

Gbajugbaja oṣere tiata orilẹ-ede Ghana nni, Efia Odo ti sọ pe oun fẹran lati maa gbe idaji ihoho oun sita, paapaa lori ayelujara, nitori pe nnkan to n foun nifokanbale ju nigbesi aye oun niyẹn.

Ọmọbinrin ti ko fi bẹẹ sanra naa sọ pe ko si nnkan meji to fa a ju boun ko ṣe sanra rara, to si jẹ pe ka ni oun sanra daadaa, o ṣee ṣe koun ma le gbe fọto idaji ihoho ara oun sita, nitori pe ko nii ba oun lara mu rara.

Efia Odo to tun jẹ gbajumọ lori afẹfẹ lorilẹ-ede Ghana naa tun fi kun ọrọ rẹ wi pe bo tilẹ jẹ pe oun ko fẹran lati maa ṣi ara oun silẹ nita gbangba, ṣugbon toun fẹran lati maa ṣi idaji ihoho ara oun silẹ, paapaa boun ba n lọ laarin opopona.

Bẹẹ lo tun tẹsiwaju pe lara awọn aṣọ toun fẹran lati maa wọ ni aṣọ ti wọn fi n wẹ ninu odo igbafẹ, iyẹn Bikini nitori pe ọmọ Ghana loun jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI