KỌỌTU TI AKINLADE N GBE GOMINA ABIỌDUN LỌ LO N DA IṢẸ DURO NIPINLẸ OGUN - AFỌLABI AFUAPẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 20, 2019

KỌỌTU TI AKINLADE N GBE GOMINA ABIỌDUN LỌ LO N DA IṢẸ DURO NIPINLẸ OGUN - AFỌLABI AFUAPẸ

Kọmiṣana fọrọ ọdọ ati ere idaraya, Ọnọrebu Afọlabi Afuapẹ ti sọ pe ko si nnkan meji to n da iṣẹ idagbasoke duro nipinlẹ Ogun latigba ti Gomina Dapọ Abiọdun ti jawe olubori loṣu karun ọdun yi bi ko ṣe ti ile ẹjọ ti oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Abdulkabir Akinlade n gbe ijọba lọ.

Lonii ni Ọnọrebu Afuapẹ sọrọ naa nibi eto tẹgbẹ oṣelu APC gbe kalẹ nile ẹgbẹ wọn to wa ni Okejigbo niluu Abẹokuta, nibi tawọn oludije sipo alaga ati kansẹlọ kaakiri ijọba ibilẹ ti foju ara wọn han.

Afuapẹ sọ pe ile ti Ọlọrun kọ ni Gomina Dapọ Abiọdun, ṣugbọn ti gomina ana, Ibikunle Amosun kọ lati mọ, idi ni yii toun ati ọmọ rẹ nidi oṣelu ṣe fidi rẹmi sọwọ Gomina Abiọdun nibi idibo to kọja.

Siwaju sii lo sọ pe bi kii ba a ṣe ti ile ẹjọ ti Ọnọrebu Akinlade n gbe Gomina Abiọdun lọ ni, iṣẹ ko ba ti lọ ju bayii lọ nitori pe awọn owo to yẹ kawọn fi ṣiṣẹ lawọn fi n ṣe ẹjọ ni kọọtu, to si lawọn tun ti wa nile ẹjọ giga agba (Supreme Court) bayii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Wọn gbe Gomina Dapọ lọ sile ẹjọ Tribunal, Ọlọrun ju wọn lọ nibẹ, wọn tun gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, ti Ọlọrun si tun jẹri ara rẹ. Ni bayii, a tun ti wa nile ẹjọ agba niluu Abuja bayii. Bi ẹnikẹni ba wo bi Dapọ ṣe di Gomina lonii, wọn a mọ pe iṣẹ Ọlọrun ni, iṣẹ Oluwa si re e, ko ṣee tu wo.

"Gomina Dapọ Abiọdun n ṣiṣẹ lọwọ, bi kii ba a ṣe ti ile ẹjọ ti a n lọ ni, awọn iṣẹ naa yoo ti ju bayii lọ, niṣẹ la bẹ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lati farabalẹ. Kii ṣe pe ẹru lo n ba wa nitori pe awa mọ pe a ko yi ibo wọn, ṣugbọn awọn owo ti wọn n jẹ ka maa danu sile ẹjọ, ti wọn ko jẹ ka ri oju raaye lati ṣe ijọba lo n dun wa, kii ṣe pe boya wọn ni ẹjọ ti wọn fi fẹẹ fi tan wa jẹ.

"Ọlọrun lo gba adura wa, kii ṣe wipe a mọn ọn ṣe. Gomina Abiọdun ti n tun awọn ile ẹkọ ṣe kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ patapata, bẹẹ lawọn ile iwosan agbegbe kaakiri ijọba ibilẹ ko gbẹyin ninu awọn iṣẹ to n lọ lọwọ. Lara rẹ tun ni eto aabo, igbanisiṣẹ, tawọn PWA naa ti n ṣe opopona kaakiri.

"A ni lati da ara wa lẹkọọ wipe ẹyọkan ṣoṣo ni ẹgbẹ oṣelu APC, ati pe wahala to wa laarin wa lasiko yi, a maa yanju ẹ ni. Ọpọ igba lati jokoo lati rii pe wipe ko si nnkan to pin wa laarin gbungbun ipinlẹ Ogun."

"Ahesọ kan ti wọn tun n gbe kaakiri bayii ni pe wọn ti kọ orukọ awọn igbimọ, ko si nnkan to jọ bẹẹ rara, ti wọn ba n tan yin jẹ lati gba owo lọwọ yin, ẹ ma da wọn lohun rara, ko si bi wọn ṣe maa kọ orukọ ti iru emi yi ko nii mọ sii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI