Oludije sípò Gomina nipinlẹ Ogun lẹẹmeji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Ọtunba Olurotimi Paṣeda tí pariwo síta wípé digbi lòun wá, tí kò sì nnkan tó ṣe òun gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ẹlẹjẹ táwọn èèyàn ń gbé káàkiri nípa ẹ.
Kò sí nnkan méjì tó jẹ́ kí ọkùnrin gbajumọ oníṣòwò tó tún jẹ́ olóṣèlú náà pariwo síta bí kò ṣe ti ahesọ ikú ẹ ti wọn làwọn kan ń gbé káàkiri, àti wípé ìrònú bí kò ṣe wọlé idibo tó kọjá yí lo pa a.
Paṣeda nígbà tó ń bá ọkàn lára àwọn akọroyin nipinlẹ Ogun sọ̀rọ̀ lórí ahesọ naa sọ pé orilẹ-èdè Mexico níbi tòun ni ileeṣẹ sì lòun wá, láti mojuto àwọn nǹkan tó ń mú owó wọlé foun.
Abẹ asia ẹgbẹ́ òṣèlú UPN ni Ọtunba Rotimi Paṣeda tí kọkọ jáde dupo Gomina, níbi tó ti ṣe ipò Kẹta, tó sì tún jáde dupo náà lọ́dún yí, to sì tún fìdí rẹmi kọjá afẹnusọ.
AWIKONKO gbọ́ pé ìdí táwọn èèyàn fi ń gbé ìròyìn ẹlẹjẹ káàkiri nípa Paṣeda tó tún jé ogunna-gbongbo ojiṣẹ Ọlọ́run ní wọn kò ṣe gburo rẹ mọ látìgbà tí idibo tí kọjá lọ.
No comments:
Post a Comment