KAYEEFI NLA, WỌN JU ỌMỌDUN MẸẸDOGUN SẸWỌN LEKOO, WỌN LAWỌN ỌLỌPAA LO PURỌ MỌN ỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 7, 2019

KAYEEFI NLA, WỌN JU ỌMỌDUN MẸẸDOGUN SẸWỌN LEKOO, WỌN LAWỌN ỌLỌPAA LO PURỌ MỌN ỌN

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ko tii sọ nnkankan lori awuyewuye to n lọ lori ọmọdun mẹẹdogun kan ti wọn ju sẹwọn niluu Ekoo, sibẹ, epe nla-nla lawọn to gbọ siṣẹlẹ naa n gbe awọn ọlọpaa ṣẹ lori bi wọn ṣe ọmọ naa sẹwọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ole ni ọmọ naa ti mama ati baba rẹ ti ku lọọ ja nitori ounjẹ ti ko ri jẹ, ṣugbọn ti ọwọ ọlọpaa pada tẹ ẹ, ti wọn si fẹsun kan an.

Ohun to ṣeni ni kayeefi pupọ ni pe ọmọdun mẹẹdogun (15) ni ọmọ naa ti a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko yi, ṣugbọn ti wọn lawọn ọlọpaa to wa nidi ọrọ rẹ sọ pe ọmọdun mejidinlogun ni lati le fiya jẹ ẹ.

Ori ikan ni ayelujara ti Nairaland tiroyin naa ti ta si AWIKONKO leti lawọn to ri aworan ọmọ naa ti n gbe awọn ọlọpaa ṣepe lori iwa ti wọn hu naa.

Wọn yi lohun tawọn eeyan sọ lori rẹ: ỌMỌDUN MẸẸDOGUN TI WỌN JU SẸWỌN

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI