IWADII TI BẸRẸ LORI BAWỌN ADIGUNJALE ṢE FẸMI ṢOFO DANU L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 22, 2019

IWADII TI BẸRẸ LORI BAWỌN ADIGUNJALE ṢE FẸMI ṢOFO DANU L'EKITI

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ ni kikun lori idunjale to waye ni Banki UBA to wa nikorita T to wa niluu Ọyẹ-Ekiti, ipinlẹ naa l'Ọjọbọ Tọside ana.

Ọmọdebinrin kan ati gendekunrin kan la gbọ pe wọn ba ijamba naa lọ nigba ti biọn ba wọn nibi ti wọn duro sii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Celeb Ikechukwu sọ pe awọn ọlọpaa kogberegbe, iyẹn SARS ti bẹrẹ iwadii lati mu awọn to ṣiṣẹ, toun si nigbagbọ wipe ọwọ yoo tẹ wọn laipẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe oun ko le fidi ẹ mulẹ boya wọn ri owo ji gbe lọ, ṣugbọn nnkan to da oun loju ni pe kii ṣe iṣẹ ọjọ kan lawọn ọdaran naa ṣe ki wọn too digun wa. O fi kun un wipe gbogbo agbaye ni yoo gbọ nigba tọwọ palaba wọn ba segi.

Image may contain: one or more people, people standing and outdoor





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI