IPINLẸ OGUN ṢETAN LÁTI SAN ẸGBẸRUN LỌ́NÀ ỌGBỌ́N OWÓ OṢÙ TUNTUN- GÓMÌNÀ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 28, 2019

IPINLẸ OGUN ṢETAN LÁTI SAN ẸGBẸRUN LỌ́NÀ ỌGBỌ́N OWÓ OṢÙ TUNTUN- GÓMÌNÀ ABIỌDUN


Ọmọba Dapọ Abiọdun tó jẹ́ Gomina nipinlẹ Ogun tí fìdí ẹ múlẹ̀ wípé ìjọba òun ti ṣetan láti san owó ọ̀yà tuntun tó kéré julọ, èyí tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n fáwọn òṣìṣẹ́ pátápátá. 


Gomina Abiọdun lo fìdí ọ̀rọ̀ yi múlẹ̀ l'Ọjọru (Wẹside) àná níbi ifilọlẹ ilé ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àgbà, ìyẹn Association of Senior Civil Servants of Nigeria (ASCSN), èyí tó wà ní Magbọn, Abẹ́òkúta.


Ó ní bo ṣé jẹ́ pé ìjọba òun karamasiki nípa àwọn òṣìṣẹ́, táwọn sì ṣetan láti gbajumọ àwọn nǹkan tó nii ṣe pẹluu àwọn òṣìṣẹ́, ìdí nìyí tijọba yóò fi san owó oṣù tuntun náà.

Bákan náà lọ tún sọ pé gbogbo àwọn nǹkan tó bá nii ṣe pẹluu ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ lòun tún ti ṣetan láti gbeyẹwo dáadáa, kí àtúnṣe sì wá fún wọn.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI