Ọjọ tawọn araalu Ekan Meje to wa nijọba ibile Oke-Ero nipinlẹ Kwara ko le
tete gbagbe lọjọ Ẹti (Furaidee) ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹẹdogun oṣu
kọkanla nigba ti ile-ẹkọ giga ti wọn ti ń kọ nípa eto ilera lọ́nà ìgbàlódé tuntun nni, Davest
College of Health Technology ṣe ayẹyẹ igbaniwọle fawọn akẹkọọ tuntun wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹsẹ ko gbero ni gbogbo ilu
Ẹkan lọjọ naa pẹluu bi wọn ṣe lawọn agba oloṣelu atawọn ọtọkulu lawujọ
bii, Abẹnugọn ile igbimọ ipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Yakubu Salihu Danladi;
Oludari ile ifowopamọ ti First Bank to wa ni Omu Aran, Ọgbẹni Alayande
Adedamọla; Ọga agba ile ẹkọ ilera giga tipinlẹ naa, (Kwara State College
of Nursing) ko gbẹyin nibẹ.
Awọn min in tun ni Ọnọrebu Tunji Ọlawuyi
Ajuloopin to n ṣoju agbegbe Iṣin/Irẹpọdun/Ekiti/Oke Aro nile igbimọ
aṣoju-ṣofin tiluu Abuja; Akọwe agba ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto
ẹkọ, Ọmọwe Musa Ọladimeji Dasuki atawọn min in.
Ko si nnkan meji to jẹ ki ọjọ naa larinrin ju bawọn eeyan ti lero lọ ni bo ṣe jẹ pe akọkọ iru ẹ ni ayẹyẹ igbaniwọle náà ti wọn ṣe fawọn akẹkọọ ti ko din ni marundinlaadọrin (65) àkọ́kọ́ wọn.
Nigba to n gbe oṣuba kare fun fun ọga agba ile ẹkọ naa, Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Yakubu Danladi ti igbakeji rẹ, Ọnọrebu Adetiba Ọlanrewaju ṣoju fun sọ pe ki idagbasoke to le de ba eto iṣuna orilẹ-ede tabi ipinlẹ yòówù, afi kawọn aladani ko ipa ti wọn.
“Inu mi dun wi pe ile ẹkọ giga akọkọ de agbegbe Oke Ero, ti wọn si tun ṣe ayẹyẹ igbaniwọle fawọn akẹkọọ ti wọn kọkọ gba wọlé láti fi bẹ̀rẹ̀ sáá ikẹkọọ tuntun tọdun 2019 sì 2020. Nnkan ayọ nla ni wi pe iru idagbasoke bayii n wọle lasiko yi, paapaa bo tun ṣe jẹ agbegbe ti mo ti wa. O wu mi loori wipe mo tun jẹ alejo pataki.”
Siwaju sii lo gbawọn akẹkọọ tuntun naa lamọnran wipe ki wọn lo anfaani ẹkọ ti wọn ba kọ lati fi mu idagbasoke ba orilẹ-ede wọn, ati pe wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ igbe aye tuntun ni.
Bakan naa ni Ọnọrebu Tunji Ọlawuyi Ajuloopin to n ṣoju agbegebe Irẹpọdun/Iṣin/Ekiti/Oke-Ero nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti Ọgbẹni Gani ṣoju fun naa ṣeleri wipe gbogbo iranwọ to ba wa nikawọ oun loun yoo ṣe lati tubọ ran ile ẹkọ naa lọwọ, tori pe idagbasoke ati ilọsiwaju lo jẹ oun logun.
Ṣaaju asiko yi, alakoso ile ẹkọ giga naa, Ọmọwe Oluṣẹgun David Awolẹyẹ dupẹ lọwọ gbogbo awọn alejo, paapaa awọn alejo pataki ọjọ naa fun bi wọn ṣe bọwọ fun wọn lati wa nibi ayẹyẹ naa.
O ni gbogbo agbegbe naa lawọn fẹẹ mu idagbasoke ba, paapaa nipa awọn idanilẹkọọ wọn.
Nígbà tó ń ṣe ibúra fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tuntun náà, olugbaniwọle ilé ẹ̀kọ́ yí, Jọlayẹmi Abiọdun Rotimi sọ pé dandan ni ki wọn maa fi ìbúra àti ijẹwọ wọn sọkan ni gbogbo igba láti má bàa tàpá sì òfin tó gbà wọn wọlé nítorí pé ìlú tí kò sì òfin ni wọn kii ni ẹṣẹ.
Lara awọn to tun wa nibi ayẹyẹ naa ni Ẹlẹkan tiluu Ẹkan, Ọba Adeyẹmi Aroyinkẹyẹ; Akọwe agba lẹka eto ẹkọ, Ọmọwe Ọladimeji Dasuki atawọn min in.
No comments:
Post a Comment