IDI TI MO ṢE FI MÁJÈLÉ PA ỌMỌ-ỌMỌ MI DANÙ, Ẹ DARI JI MI - ỌDAJU ABIYAMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 25, 2019

IDI TI MO ṢE FI MÁJÈLÉ PA ỌMỌ-ỌMỌ MI DANÙ, Ẹ DARI JI MI - ỌDAJU ABIYAMỌ


Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn to gbọ si'ṣẹlẹ kayeefi naa ni wọn ṣi n ṣepe rabandẹ-rabandẹ fun iyaale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Temitọpẹ Akinọla, ẹni ọdun mejilologoji (42) ti wọn loo pa ọmọ-ọmọ rẹ danu, sibẹ obinrin naa ni oun lọrọ lẹnu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọjọbọ (Tọside) ọsẹ to kọja yi ni wọn sọ pe Temitọpẹ fun ọmọ-ọmọ rẹ to jẹ ọmọ ọjọ meji naa ni oogun apẹfọn (Sniper) mu lagbegbe Iṣọtẹ niluu Ṣagamu, to si ṣeku pa ọmọ naa danu.

AWIKONKO gbọ pe latigba ti ọmọ Temitọpẹ, ti wọn pe ni Wasilat to bimọ yi ti loyun ni wọn ni ko ti gba ti ẹni to loyun fun, to si gbiyanju titi lati yọ oyun daanu. Gbogbo akitiyan ti wọn ni Temitọpẹ gba lati jẹ ki oyun ti ọmọ rẹ ni yii lo ja si pabo, ko da, ti wọn ni Pasitọ ṣọọṣi to n lọ tun sọ fun un pe ko gbọdọ gbiyanju ẹ wo.
Idi ni yi ti wọn loo fi duro de asiko ti ọmọ rẹ yoo bimọ.

Awọn to gbe iṣẹlẹ naa si AWIKONKO leti sọ pe ko pẹ ti Wasilat fun ọmọ tuntun lọmu tan lo gba baluwẹ lọ lati lọọ wẹ, asiko yi gan an ni wọn ni Temitọpẹ gbe oogun apẹfọn to ti ra si baagi rẹ jade, to si fun ọmọ naa mu. 

Igbe la gbọ pe o ọmọ naa sun to fi jade laye. Ariwo ọmọ naa lo mu ki Wasilat tete jade ni baluwẹ to si jẹ pe nigba ti yoo fi jade, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ. Ara ti wọn loo fu iya ọmọ tuntun yi lo jẹ ko gboorun ẹnu ọmọ rẹ, to si ṣakiyesi wipe ẹnu rẹ n run fun majele.

Loju ẹsẹ ni wọn loo ti lọ mọ Temitọpẹ lọrun wipe afi ko ba oun ji ọmọ oun, nitori toun mọ wahala ati iya toun jẹ koun too bimọ yi. Ki oloju too ṣẹ la gbọ pe gbogbo adugbo ti pe le wọn lori, ti wọn si lawọn araadugbo sare kan sawọn ọlọpaa.

Nigba tawọn ọlọpaa n fọrọ wa Tọpẹ lẹnu wo, o ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ eṣu ni, sibẹ ko si nnkan meji toun fi kan gbe igbesẹ ni ti ẹni tọmọ oun bimọ fun, nitori pe oun ko le la oju oun silẹ kawọn mejeeji fẹ ara wọn. Lateef ni wọn pe orukọ ẹni ti Wasilat loyun fun, to si fi bimọ obinrin.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe wọn ti gbe oku ọmọ naa lọ si mọṣuari ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ to wa niluu Ṣagamu fun ayewo ara oku, to si tun sọ pe Temitọpẹ yoo foju bale ẹjọ laipẹ lẹyin iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI